Home iroyin Àwọn asòfin Abuja sọ Fashola di bọ́ọ̀lù, wọ́n ń gbá a síra wọn
iroyin - July 6, 2017

Àwọn asòfin Abuja sọ Fashola di bọ́ọ̀lù, wọ́n ń gbá a síra wọn

 

Bi igba ti oluko n ba omo kilaasi re soro ni opo awon omo Ile Igbimo Asofin Agba ti a mo si National Assembly se n soro si Minisita fun Oro Ise, Agbara ati Ilegbee, Ogbeni Babatunde Fashola, bayii o.

Bi awon kan se n soro si i ni ile asofin kekere ti House of Assembly ni won n laali re ni Seneeti.

Ohun to da ija sile laarin won ni bi Fashola se fesi ibinu si won nigba ti won ge owo ti ile ise re pin fun atise ona Lagos-Ibadan Expressway ati ona Apapa-Wharf, ti awon mejeeji je eyi to se pataki fun oro aje orile-ede yii.

Nigba ti oun bu bii ogbon bilionu fun ona Eko si Ibadan, awon asofin naa yo ada ti i, ti won sig e sib ii bilionu mewaa.

Eyi bi Fashola ninu, to si so pe nnkan buruku ni won se.

Lara ohun ti o je ko so bee ni pe ijoba apapo n je awon kongila to n se ona naa lowo pupo tele.

O so pe o seni laanu pea won asofin naa bu owo si ise ti ko si ninu bojeeti tele, to si je pe dipo ti atunse awon ona nla-nla kiba fi je won logun, awon kanga giriwo borehole lo mumu laya won.

Atigba to ti so eyi ni ogun ti gbebon, tori awon asofin naa gba pe o yeye awon ni.

Awon House of Assembly ti pase pe ki Fashola wa ri awon lati wa gbo oro gidi. Bee naa ni awon Seneeti n fapa janu.

Senito Danjuma Goje so ran Fashola lo sile lojo Alaaruba, nigba to so fun un pe ko ma ro pe Ipinle Eko nikan ni oun je minisita le lori o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…