Home ÀKỌ̀TUN Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lẹ́yìn ikú Adeleke
ÀKỌ̀TUN - July 5, 2017

Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lẹ́yìn ikú Adeleke

 

…. aburo oloogbe da atako PDP ati APC pada

Nje apa Aregbe maa ka ibo to n bo yii abi oku aja Adeleke yoo  jeko jaaye lo?

 

Bo ba je pe loooto ni oku le ma sun lorun, o seese ko je pe kedere ni oku gomina Ipinle Osun tele, Senito Isiaka Adeleke, yoo laju sile lohun-un bayii.

Idi ni pe yoo fe mo ibi ti ibo senito to fe waye ni Ipinle Osun yoo yori si.

Adeleke di oloogbe ni nnkan bii ose meloo seyin, laije pe o se aisan kan lo titi.

O n mura fun ibo gomina leekan sii ni nigba naa ni olojo de ba a.

Leyin opo awuyewuye, aburo re kan, Alagba Ademola Adeleke, pinnu lati lo gba ipo ti egbon re fi sile ni Seneeti ni Abuja.

Sugbon egbe oselu ti Adeleke wa ko to ku, iyen APC, ko fun un laye bee.

Dipo re, won yan Alagba Mudashiru Hussein gege bii asoju won ninu ibo naa. Eyi bi Ademola ati awon ebi Adeleke ninu debi pe won pinnu pe o gbodo lo dije ninu egbe PDP.

Eyi lo fa a ti oro ibo naa tun fi fe le bi ogun agbede.

Wahala laarin egbe mejeeji kii ro teletele, tori opo eniyan lo ranti bi nnkan se le koko laye idije Gomina to wa nipo bayii, Ogbeni Rauf Aregbesola, ati Gomina ana, Omooba Olagunsoye Oyinlola.

Bawo wa ni ibo yoo se lo ni Satide to n bo? Awon nnkan to le sise fun Ademola Adeleke ni aanu ti awon oludibo kan le fe ni fun egbon re to ku.

Bakan naa, owo ko le je e niya tori okan lara ebi naa je olowo gidigidi. Onitoun ni Alagba Adedeji Adeleke, eni to je baba akoriin hip hop ti a mo si Davido.

Ohun kan ti o tun le fa ki awon eniyan kan fe fajuro si Aregbe ni pe ijoba je won ni owo osu. Boya idi niyi ti awon to ti feyinti lenu ise oba, sugbon ti won ko tii ri owo osu gba fi n se iwode kaakiri Osogbo bayii.

Sugbon sa o, o jo pe Aregbe ati APC naa wa kanpe. Lona kinni, gomina naa je eni kan ti opo eniyan nifee si pupo. A gbo pe o tun ti san ninu owo osu awon osise, to si tun ti sise gidi lori ona ati eto eko.

Ohun to tun le sise fun APC ni pe oludije fun egbe naa, iyen Hussein, naa kii se eran riro. Oun naa je oloselu to ri ese wale. Boya idi niyi to fi leri si olubadije re laipe yii pe oun gbeye lowo Oloogbe Isiaka Adeleke nigba to wa laye, ti oun si tun setan lati da aburo re naa mole.

 

Mo fe pese ise fun awon odo ni Ipaja-Ayobo – Lateef Bisimillahi

Oludije fun ipo alaga ijoba ni Ipaja Ayobo, labe asia egbe Labour Party, Alagba Olanrewaju Lateef, aka Bisimillahi, ba oniroyin wa Kehinde Sule, soro lori idi ti o fi fe ki awon eniyan dibo fun oun

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…