Awon onisegun ibile ni awon le wo Buhari san
… won ni oogun awon lo je ki Obasanjo maa ta pon-un-pon-un
Awon agbajo onisegun ibile ni orile-ede yii ti ke si Aare Muhammadu Buhari pe awon setan lati so oke isoro re di petele lori ailera to n ba a ja.
Won ni ko si arun ti apa Olorun ko ka ti a ba tele ilana ti awon baba wa.
Babaasale egbe awon tewe-tegbo naa, labe asia egbe National Association of Nigerian Traditional Medicine Practitioners, Dokita Adesunmiboye Fawawo, lo so eyi di mimo lojo Isegun nigba ti won n gbe opa ase le awon adari egbe naa tuntun lowo.
Fawawo ni awon setan lati pa itu meje ti olode e pa bi ijoba apapo ba fun awon laye lati se itoju olori orile-ede yii.
Won ni lasiko ijoba Oloye Olusegun Obasanjo ni won da egbe awon sile.
Fawawo se alaye pe Obasanjo ko ko iyan awon kere, to si je pe awon n mi si i lara daadaa.
O ni idi niyi to fi je pe ojoojumo ni ara Obasanjo n le koko bi ota, to je pe bi o tile je pe o ti le ni ogorin odun, o sit un n tap on-un-pon-un bii omo ogun odun ni.
Orile-ede United Kingdom ni Aare Buhari ti n gba iwosan.
O ti fee to osu meji ti o ti wa nibe, ti awon kan, paapaa Gomina Ayo Fayose ti Ipinle Ekiti, si n so pe nnkan tii fe bowo sori.
Sugbon sa o, awon abenugan ijoba bii Minisita fun Oro Iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed, fi n da omo Naijiria loju pe Olorun ti n gbakoso lori ailera Aare.
Won ni adura ni ki awon omo Naijiria tubo maa fi ran Aare lowo.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…