Home iroyin Fatai Alimi: Ogbologbo birikila to fun iyawo oluko yunifasiti loyun
iroyin - July 4, 2017

Fatai Alimi: Ogbologbo birikila to fun iyawo oluko yunifasiti loyun

 

Nigba miiran, awon nnkan maa n sele to je pe yoo kan maa se eniyan ni kayefi ni.

Koda, to ba sele ninu fiimu, awon gbenu-gbenu oluworan le maa so pe iro ni, ko le sele loju aye.

Sugbon isele nla kan ti se ni ilu Eko bayii o.

Arakunrin birikila kan, Ogbeni Fatai Alimi, ti gba iyawo oluko kan ni Yunifasiti ti Ipinle Eko, iyen Lagos State University, Ojo, Ogbeni Suraju Oyekunle.

Ere tabi awada ni Ogbeni Suraju koko pe oro yii nigba ti obinrin naa, Iyaafin Kafayat sa lo si odo Fatai.

Sugbon nigba ti won ri awon mejeeji, Kafayat ni Fatai ni oun yan laayo bayii; bee Kafayat naa ti bi omo kan fun oluko naa tele.

Pabambari ibe ni pe obinrin naa ti loyun fun Fatai bayii, to si je pe ile re lo wa.

O ni ohun to le oun koro lodo Suraju ni pe lati nnkan bii odun metala ti awon ti bi omo kan, oun ko ri omiran bi mo.

Sugbon bi oun ati Suraju se rira ni Olorun da oun lohun.

Ki a ma fa oro gun, Kfayat ati Fatai n reti omo lanti-lanti bayii.

Aworan Fafayat, Suraju ati Fatai lo wa ninu foto yii. Fatai ogbologbo birikila ni o se irungbon sesere yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…