Home LÁGBO ÀRÍYÁ Badoo: Nje Lamide ko ni pa oruko re da bayii o?
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 4, 2017

Badoo: Nje Lamide ko ni pa oruko re da bayii o?

 

Pelu wahala ti awon asebi kan n da sile, paapaa ni ilu Ikorodu, nje akorin hip hop pataki, Olamide, ko na lati pa inagije re da bayii o.

Olamide ni gbogbo eniyan mo si Badoo, bi won se mo D’Banj ni Koko Master, ti Pasuma si n je Oga Nla.

Sugbon awon janduku naa ja oruko ohun gba lowo Olamide, ti won n pa awon eniyan ni ipakupa ni Ikorodu.

Opo eniyan ni won ti fi bee ran lo sorun apapandodo.

Oru ni won maa n ka onile mole, ti won yoo si pa atiya, ati baba, ati omo ni apalado.

Awon olopaa ati ijoba Ipinle Eko ti n sapa lati gbe awon karanbaani naa de; koda, Gomina Akinwunmi Ambode ti yoju sibe.

Awon araalu naa ti lo ra opolopo ada ati ibon, tori oro naa ti de oju gongo.

Ni pataki, nje Olamide ko ni lati wa apeje miiran je bayii?

Kin ni ero ti yin? Bee ni, abi bee ko?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…