Home LÁGBO ÀRÍYÁ Ojo ti mo koko foju kan Mercy Aigbe ni ife re ti wa lokan mi – Lanre Gentry
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 2, 2017

Ojo ti mo koko foju kan Mercy Aigbe ni ife re ti wa lokan mi – Lanre Gentry

 

Bi o tile je pe ija nla ti be sile laarin osere fiimu Mercy Aigbe ati oko re, Lanre Gentry, okunrin naa si gbagbo pe alaafia si le pada si aarin awon.

Koda, bo tile je pe Mercy Aigbe ti ko kuro nile lati ose die seyin, Lanre ni kootu kankan to tii tu igbeyawo awon ka.

Mercy Aigbe so pe alupamoku ni Lanre maa n na oun, to si je pe opolopo foto lo ti se afihan re, nibi ti oju ati enu re ti wu, ti eje si fe maa da jade, wa lati fihan pe ika eniyan ni okunrin naa.

Sugbon nigba to n soro ninu iforowanilenuwo kan lojo Sunday, Lanre ni iro funfun balau ni pe oun maa n na Mercy.

O ni loooto ni ede aiyede be sile laarin awon lasiko odun Easter to lo, sugbon oun ko lu u.

O wa fi kun un pe eniyan gidi gba a ni awon obi obinrin naa, debi wi pe won si maa n ba oun soro, ti won si n gbe igbese ki ija pari laarin oun ati Mercy.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…