Home Orisirisi Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ dókítà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gba ipò kínní lókè òkun
Orisirisi - July 1, 2017

Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ dókítà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gba ipò kínní lókè òkun

Awon akekoo onimo isegun igbalode ti won ro pe omi ti tan leyin eja awon ni ijoba Ogbeni Rauf Aregbesola se iranlowo eto eko fun lo si orileede Ukraine. Odu ni Fasiti naa loke okun, V.N Karazin Kharkiv National University, Kharkiv, Ukraine  wa lara awon Fasiti adayeba. Odun 1804 ni won da ileewe naa sile ni eyi to tumo si pe o ti lo le odun okoolelugbadin-meje (213 years). Gbogbo awon omo aadota ti won lo lati ipinle Osun pata lo jawe olubori.

Arabinrin Oyeleye Lateefah Abiola ni jojolo dokita to jawe olubori ju. Apapo maaki re je ida merindinlogorun-un (95.6%) ninu ogorun-un. Omo naa fere mo ti elomiran mo iwe re.Bi idunnu se n sele ni orileede Ukraine lowo-lowo naa lo n sele ni ipinle Osun ati ni ile awon omo aadota naa.

Ileewe naa loruko de bi wi pe, o ti pese akoni meta to gba ami eye litireso iru eyi ti ojogbon Wole Soyinka gba fun Naijiria.

Ibi ayeye asekagba naa ni orileede Ukraine

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…