Home Orisirisi Ọpẹ́ o! Naijiria ti ń ta isu sí ìlú London
Orisirisi - June 29, 2017

Ọpẹ́ o! Naijiria ti ń ta isu sí ìlú London

Fun igba akoko lati aimoye odun seyin, orileede Naijiria ti n ko isu jije lo si ilu Oyinbo ni eyi to maa mu ki a gba owo to ni itumo wole fun oro-aje wa to denu kole. Toonu mejilelaadorin (72 tonnes) lo n jade kuro ni orileede yii laarin ose meji si meta bayii. Gbogbo eto bi awon isu naa o se ni baje lo si ti wa ni sepe.

Minisita fun eto-ogbin tun fi da awon ara ilu loju pe opo ounje ni a fi n sofo ni ilu wa yii nitori pe a n pese ju ohun ti a le je tan ni eekan naa lo. O ni isoro to foju han ju ni pe ko si iselojo tabi bi a se le toju re di igba ti a ba nilo re. Eyi si wa lara ohun ti o je ijoba yii logun ju.

Ana ode yii naa ni Ogbeni Audu Ogbe salaye pe a ko ni pe maa ko eso kasu lo si oke okun ni opo yanturu, nitori pe ijoba apapo ti gbin igi kasu sare oko repete fun idagba-soke oro aje wa.

Ijoba apapo si tun n fi da ara ilu loju pe ki won ma se beru rara pe boya oda ounje le wa, o ni ko si ohun to joo. O ni ajeyo ati ajeseku ko ni dawo duro rara. Eyi ti o kan le sofo ni ijoba maa se lojo fun tita si oke okun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…