Home Orisirisi Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ṣe pàtàkì – Babangida
Orisirisi - June 28, 2017

Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ṣe pàtàkì – Babangida

Aare ologun tele ri ni orileede yii, Ajagunfehinti Ibrahim Babangida naa ma ti da si oro orileede yii. O ni agba kii wa loja, ki ori omo tuntun o wo. O ni “agbara ko lohun o nile wo, afi ki onile ma se gba fun un”.

O ni atunto gidi gbodo tete sele ni ilu yii ki o to bo si ori. O ni orisiirisii iroyin lo ti n lo labenu nipa eleya-meya pelu elesin-mesin, ohun kan gbogi to si le koko segun re ni olopaa ipinle. O ni awon omo ipinle lo maa se olopaa ipinle won ni eyi to maa je ki aabo to gbopon wa ni iru ipinle bee, nitori pe “oloju ko ni la oju re sile ki talubo ko woo”.

Babangida ni atunto kiakia ti gbogbo awon ojogbon ti n pariwo ti to asiko bayii, bi o tile je pe atunto ti awon eniyan ti n soro tele ni lati se pelu “National Confab” to waye ni odun 2014 labe isakoso ijoba Goodluck Jonathan.

Awon ara ilu fe ki ijoba APC ma se fi ti oselu see, ki won je ki atunyewo waye lori abajade ipade naa, ki a si di awon koko to ba le se ilu lanfani mu nibe. Lara ohun ti awon ojogbon ni o wa nibe ni isejoba tabi idibo ti ko ni si baba isale, to fowo si olopaa ibile, to fowo si olopaa ipinle, isejoba ti o maa din agbara Abuja ku, isejoba ti amajuto ara ilu maa wa nibe ati bee bee lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…