Home iroyin Iku awon omo yunifasiti mokanla fa ibanuje nla
iroyin - June 28, 2017

Iku awon omo yunifasiti mokanla fa ibanuje nla

 

…Leyin ose kan ti Fatile Emmanuel ku sinu swimming pool ni OAU, Ife, Olaitan naa b’omi lo ni UNILORIN

…Boko Haram pa mesan-an ni fasiti Maiduguri

 

Afi ki Olorun re obi awon omo yunifasiti ti won n pade iku ojiji lekun ni o.

Laarin ose bii meji sira won, omo yunifasiti mokanla ototo ni won pade iku airotele, ti ibanuje si gba okan awon obi won.

Ko si bi ibanuje ko se ni joba lokan iya ati baba to jiya pupo lati to omo lati kekere, to jiya lati ri i pe omo naa paasi JAMBU, to wa dip e onise ojiji je pe omo naa ti di oloogbe, ti oniwaju keyin, ti eleyin siwaju.

Gege bee ni ti awon obi Olaitan Bolaji Samshedeen, omo ile iwe Yunifasiti ti Ilorin to ku sinu omi nigba ti oun ati awon akegbe re lo we lojo Monday.

A gbo pe Olaitan ko mo iwe we, sugbon awon ore re kan lo pon on ni dandan fun un lati kan ludo.

Isele buruku yii waye leyin bi ose kan ti omo ile iwe Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Fatile Emmanuel, naa ku sinu odo alafowoda swimmipin pool ni oteeli kan ni Ife.

Oun tile mo bi eniyan se n luwee, isele to se si i fihan pe loooto odo ti eniyan ba foju rena lo maa n gbe ni lo.

Bee, iku ogun lo maa n pa akikanju, ti iku odo n pa omuwe.

Ajalu miiran tun sele ninu ose kan naa nigba ti awon alakatakiti Boko Haram rojo bombu ni fasiti ti Maiduguri.

Omo ile iwe naa mesan-an ototo ni won di oloogbe ninu isele naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…