Home Orisirisi Ọwọ́ tẹ Sójà tó ń sisẹ pẹ̀lú Ajínigbé Evans
Orisirisi - June 27, 2017

Ọwọ́ tẹ Sójà tó ń sisẹ pẹ̀lú Ajínigbé Evans

Evans ni ajinigbe to tii lowo ju lorileede yii ni ile toni to mo yii. Bilionia ni nidii ise yii. Magodo wa lara adugbo to won ju ni orileede yii, ibe lo ko aafin re si. Ise ajinigbe o see da se lo je ki awon olopaa maa ton imole si awon ibi ti owoja re wa.

Bayii, owo awon olopaa ti te Lance Corporal Victor Chukwunonso pelu nomba idanimo 09/NA/54/6317, Bareke Abati ni adugbo Surulere ni o ti n sise. “Bi ina ko ba lalawo, ko le goke odo”. E jowo, e se mi jeje ni soja yii n wi, ko jiyan rara, koda, o ni ise meta ti oun le ranti daadaa ni eyi ti oun ti gba Milionu meji, milionu kan ati aabo pelu eketa to fun oun ni milionu meta pere.

Iwadii si tun n lo lowo lati fi owo sinkun ofin mu awon to ku to loruko nilu ti won jo n sise po pelu ogbologbo ajinigbe naa. Iroyin fi to wa leti pe owoja re de ilu oyinbo. Won ni awon kan wa ti won tun maa n fun un lowo lati ilu oba naa nipa bi awon eniyan kan se lowo to ati bi awon kan se n bo wale pelu ojo ti won n bo. Gbogbo eyi ni Evans maa n ro po to fi maa n mu eniyan sodo fun osu mefa si meje titi ti owo re fi maa pe. Bi Evans se n gba owo ti ile yii ni o n gba ti oke okun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…