Home Orisirisi Goodluck Jonathan padà sọ̀rọ̀
Orisirisi - June 27, 2017

Goodluck Jonathan padà sọ̀rọ̀

Lati bii odun meji ti Aare ana, omowe Goodluck Jonathan ti kuro lori aleefa ni ko ti ba oniroyin kankan soro ni Naijiria ati nipa Naijiria. Sugbon bayii, o ti soro, o ni ki awon odo ti o n hale ogun ati pinpin koko lo sowo agbeje mowo.

O ni, ni akoko, won ko ni je ki okan awon olori papo lati le sise gidi  ni ilu. O ni ibi aabo ati ohun ti eya kinni wi pelu idahun eya keji lo ma gba gbogbo iwe iroyin. Eyi ko si ni je ki ijoba bee ri inu nnkan gidi ro.

Jonathan tun ni, gbogbo ohun to n sele ni ilu yii bayii maa n le awon oloko owo ni ile yii ati ni oke okun. O ni ko si eni ti o le ko owo re si ibi ti aibale okan wa. O ni onitohun gbodo koko ro dukia re pelu awon osise kaakiri agbaye to fe ba oun sise.

Aare ana tun ni ki awon odo ilu yii lo sora nitori pe won ko gbon bi Olorun to da wa po gege bi orileede kan. O ni abi won ti gbagbe pe eegun ti wo inu eran ni igba ti eran naa ti wo inu eegun awon eniyan orileede yii.

Jonathan n parawo yii ni igba ti o n gba awon minisita egbe oselu PDP lalejo ni ile re to wa ni ilu Abuja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…