Home Orisirisi Màá díje du ipò Ààrẹ ní ọdún 2019, EFCC sì máa pàdánù ẹjọ́ síi – Fayose
Orisirisi - June 26, 2017

Màá díje du ipò Ààrẹ ní ọdún 2019, EFCC sì máa pàdánù ẹjọ́ síi – Fayose

Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose ni o n salaye yii fun awon oniroyin nibi ayeye odun meta re lori aleefa. Fayose ni gbogbo ejo ti EFCC n pe ni ko lese nile. Awon ejo won dabi keeta, ote ati wiwa esun ti kii se teeyan sii lese. O ni, o ti daju pe Eledua gan-an ko ni wa leyin iru ajo bee. O ni, nipa idi eyi, “ti a ba ju abebe soke ni igba, igba, ibi pelebe naa ni o si maa fi lele”.

Fayose ni oun si maa dije dupo Aare ni odun 2019 nitori ife ti awon eniyan ni si oun. O ni, eni to ba maa paro ni leleri ni orun. O ni ki won wo ero bii omi legbe leyin oun fun ayeye odun meta gege bii gomina ipinle Ekiti. O ni lati se ijoba rorun ju bi egbe oselu APC se mu lo. O ni ko ki n se nnkan to nira rara. O ni ti olori ba ti n se deede ni ilu, o ti di danadan fun iru olori bee lati ni ero leyin. O ni ti owo ba wa, je ki ara ilu mo, bi ko si, je ki won mo. O ni, o tun ye ki olori ni ife awon omo ilu bakan naa. Nitori pe ainifee awon omo ilu bakan naa lo faa ti awon eya Igbo fi fe da duro.

Fayose ni oun feti ara oun gboo ti Aare ni awon eya Igbo ko dibo fun oun rara, nipa idi eyi, awon eya naa ti ni ikun sinu si ijoba naa. Eyi si wa lara oun to n fa wahala lati odo awon eya naa.

Gomina tun ni ki won wo bi ijoba APC se doju so oun to, ki won si tun wo aseyori oun ni ilu. O ni opo ise ti awon gomina kankan ko se ri ni ipinle Ekiti lati ogun odun ti a ti da ipinle naa sile ni ijoba oun ti gbe se. Eyi si wa lara iwuri oun lati le fowo gbaya pe oun le se Aare ilu yii ti oun si maa bomi pana ote elesin-mesin ati eleya-meya to wa ni orileede yii.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…