Ọlọ́run ló gbémi lékè, kìí ṣe ikú Dagrin – Ọlamide
Gbajugbaja olorin igbalode hip hop, iyen Olamide, ti soro lori iku ogbologbo kan to fi Yoruba korin hip hop nigba kan, iyen Dagrin.
Leyin ti Dagrin – ti oruko re n je Olaitan Oladapo Olanipekun – ku tan ni irawo Olamide bere sii tan.
Eyi mu ki awon eniyan kan maa so pe bi Dagrin ko ba ku iku ojiji ni, o seese ki irawo Olamide ma tan.
Sugbon Olamide, eni ti awon eniyan n pe ni Badoo, so ninu iforowanilenuwo kan lojo Sunday pe oro ko ri bi won se n ro o yen.
O ni Olorun to maa n gbe eda leke lo gbe oun leke.
Olamide ni loooto, oloripipe akorin ni Dagrin, ti oun si se sadankaata fun un.
Sugbon o ni o ye ki awon eniyan ranti pe kii se pe Dagrin ni eni akoko to fi Yoruba ko hip hop.
Lara awon ti Olamide n so ni Lord of Ajasa.
Olamide se alaye pe lati kekere ni oun ti mo pe oun ni ebun orin, ti oun si n sise asekara lori ebun naa, lojoojumo ati nibi gbogbo.
Sugbon sa o, o tenu mo o pe oju rere Olorun lo gbe oun goke.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…