Home ERÉ ÌDÁRAYÁ BABATUNDE! Ọmọ Stephen Keshi bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti
ERÉ ÌDÁRAYÁ - June 19, 2017

BABATUNDE! Ọmọ Stephen Keshi bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti

 

Ni ile Yoruba, bi eniyan ba bi omo leyin ti baba re ba ku, won maa n so omo naa ni Babatunde, Babawale tabi Babarinde, ti omo naa ba je okunrin.

To ba si je obinrin, oruko omo naa a maa je Iyabode tabi Yewande.

Iru Babatunde naa ti de inu molebi adari agbaboolu Super Eagles to di oloogbe ni nnkan bii odun kan seyin, iyen Stephen Keshi.

Idi ni pe Olorun ti fi omokunrin lanti-lanti ta omo re ti oun naa n je Stephen Keshi Junior lore.

Arabinrin re, Aaliyah Landecho, lo bi omo naa fun un, ti oruko omo si n je Onyeka Grayson Stephen.

Bi opo eniyan se n ki Junior ati Aliyah ku oriire, adura IROYIN OWURO nip e ki Olorun woo mo naa, ki otun miiran o kun un.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…