Home iroyin Najiria setán ìrànlọ́wọ́ fún àwọn orílèèdè Adúláwọ̀ – Lai Mohammed
iroyin - June 18, 2017

Najiria setán ìrànlọ́wọ́ fún àwọn orílèèdè Adúláwọ̀ – Lai Mohammed

 

Minisita fun eto Iroyin ati Asa, Alhaji lai Mohammed, ti seleri pe Naijiria ko ni dekun ati maa se iranwo fun orileede Adulawo.

Eyi waye ni oofiisi re to wa ni ilu Abuja nigba ti o n gbalajo arabinrin Sani Koubra to je minisita fun eto igbohun-safefe ni orileede Niger.

Lai Mohammed ni ti aye ba se n yi, lo ye ki eniyan naa maa baa yi, ni eyi to mu ki ijoba Naijiria se afilole igbohun-safefe ti Radio ati Telefison igbalode Digital Switch-Over (DSO) gege bi won se n loo ni ilu Oyinbo.

Naijiria se afilole igbohun-safefe igbalode yii ni ilu Jos, ipinle Pleateu ni ogbon ojo, osu kerin, odun to koja, nigba ti afilole ti oluulu Naijiria waye ni ojo kejilelogun osu kejila, odun to koja bakan naa. Minisita si tun se ileri pe afilole tun maa koko waye ni awon ipinle mefa kan to maa fi kari orileede Naijiria.

Lai Mohammede ni gbogbo eto lo ti n lo lowo bayii lati le fi koju isoro-ki-isoro to le fe yoju latari akanse ise naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…