Home Orisirisi Ìbò 2019 ti jọba lọ́kàn Àjìmọ̀bí, Amosun, Fayose àti Arẹgbẹ
Orisirisi - June 18, 2017

Ìbò 2019 ti jọba lọ́kàn Àjìmọ̀bí, Amosun, Fayose àti Arẹgbẹ

ODUN MEJI KOJA, OSELU 2019 BERE

Ajimobi ni laipe ni oun yoo so eni t’oun a gbejoba fun

Ojudu, Fayemi n ro kuku-keke tori Fayose n pete atipadawa leeketa

Yaayi ati Yewa n finna mo Amosun l’Oogun

Ariwo Iwo Olodo Oba ko je ki Aregbe o sun l’Osun

Sugbon ewure Ambode ko l’olodi ni Eko

Bayii ti odun meji ti koja ninu odun merin ti awon to wa ni ijoba apapo ati awon ipinle yoo lo, oselu bi won yoo tun ti pada soju opon ni odun 2019  ti bere ni pereu.

Idi niyi ti awon amoye fi so pe ohun ti gomina kan ko ba se fun ilu laarin odun meji akoko, boya lo lee se e fun won mo titi yoo fi kuro nipo.

Awon igbese ti opo gomina yoo maa gbe bayii, opo re ni yoo nii se pelu idibo to n bo.

Ko kuku si ohun to kan opo oloselu ni tiwon. Ti ara won ni won koko maa n ro. Boya owe Yoruba pe bi a ba fun were gan-an ni oko lati ro oko, odo ara re ni yoo roko si.

Lati Ipinle Oyo de Osun, Ekiti de Ogun, idan orita ti bere ni pereu. Lona kinni, egbe APC lo rowo mu julo nibe. Leyin Ekiti ti Gomina Ayodele ti wa lati egbe PDP, APC lo gbe Gomina Abiola Ajimobi, Rauf Aregbesola ati Ibikunle Amosun jade. Eyi tumo si pe ninu egbe APC gan-an ni surutu yoo ti bere.

Sugbon sa o, ageku ejo ni PDP naa, o le soro bi agbon. Ni awon ipinle ti APC ti joba, o seese ki awon oloselu kan yalo sinu egbe miiran ti ina ko ba wo mo, lasiko ti awon ba fe fa eni ti yo dije fun gomina kale. Ibe ni awon egbe bii PDP, Accord ati Labour fi le taji pada. Bakan naa ni egbe  kan n bo ti won n pe oruko re ni ADP, eyi ti won fe fayo lati ara PDP, paapaa ti kooto apa Supreme Court bag be PDP le Modu Sheriff lowo.

Ni Ipinle Oyo, Ajimobi pa owe nla fun awon eniyan lose to lo, nigba to n dahun ibeere lori eto ori redio ati mohun-maworan kan. O ni awon eniyan bii merinlelogbon (34) lo ti n pete lati je gomina leyin oun.

O wa so pe laarin gbogbo won, oun ko ri eni kan to koju osunwon. Ajimobi wa fi kun un pe laipe, oun yoo fi oju eni kan han gege bi eni ti okan oun yan.

Oro yii je kayefi nla fun opo eniyan, tori o ya won lenu pe gomina naa soro gege bi eni pe oun nikan ni yoo gbe gomina tuntun jade.

Bee, Ajimobi ti so tele pe oun fara mo ki gomina to n bo o wa lati Oke Ogun. Eyi tumo si pe Ibadan yoo tun gba olide gege bi won se gba a laye Alao Akala. Nje awon oloselu nla nla to wa ni Ibadan nile OLuyole yoo gba fun Ajimobi bi? Ti gbogbo eniyan ba gba, se Ladoja a gba bee? Se Alao Akala ati awon eniyan Ogbomoso naa yo gba bee?

Ni ti Ipinle Osun, gongo ti bere sii so.  Odun to n bo, iyen 2018 ni idibo ti won. Ko di 2019.

Eni kan gbogi to fe gbo awon oloselu egbe re jigijigi tele ni Senito Isiaka Adeleke. Sugbon iku gba sika fun un ni nnkan bii osu meji seyin. Awuyewuye si n lo lori isele naa, sugbon ti eni to ku lo gbe.

Gomina Rauf Aregbesola naa ko sun lori ta ni yoo gori aleefa leyin oun. Ko si gomina tabi aare ti o maa n sun iru oorun bee. Won maa n fe ki eni ti awon fa kale wole, ko ma wa di pe iru eni bee yoo wa di esu leyin ibeji fun won.

Lowolowo yii, orin ti awon kan n ko ju ni Osun ni pe ‘Iwo lo kan’; to tumo si pe leyin ti awon ekun miiran ti je, Iwo lo ye ki o fa oludije kale bayii fun egbe APC.

O jo pe Aregbe naa fe fi ara mo eyi, bi o tile je pe oro awon oloselu ko see dola le. A gbo pe okan lara awon to wa ninu igbimo ijoba Aregbe ni oju wa lara re.

Sugbon ibeere ko tii tan lori eyi. Pelu logbologbo to fi oro aje labe Aregbe, ti awon osise ko ri owo osu gba taara, nje orin Omoluabi naa ni awon ara Osun maa ko? Ageku ejo egbe PDP nko? Ibo ni Omooba Olagunsoye Oyinlola fidi si, bo tile je pe o ti wa ninu egbe PDP?

Ekiti Kete naa ko gbeyin ninu irokuku-keke oselu naa. Awon bii Dokita Kayode Fayemi, Olusegun Oni ati Babafemi Ojudu ni awon eniyan koko fi oju si lara tele pe won a fe dije lati soju egbe APC. Sugbon oro tun ti fe beyin yo, tori Gomina Ayodele Fayose ti so pe o seese ki oun gbe apoti. Ti oro ba si ri bee, yoo fe ba eni ti APC ba fa kale na an tan gege bi owo. Osoko funra re!

Ipinnu Fayose naa je eyi to maa mu ejo die lowo. Koda, yoo fee di oro kootu. Idi ni pe o fe jo pe eleeketa ni Fayose fe je gomina niyen. Ti e ko ba gbagbe, o koko se gomina laye Obasanjo, ko to dip e won ro o loye lori esun pe o ko owo tabua je. Eekeji lo wa n lo lo bayii. Idi niyi ti loya Femi Falana ni ko seese fun Fayose labe ofin lati pada sipo.

Sugbon awon loya miiran, bii Mike Ozekhome, ti so pe ofin si gba Fayose laaye. Awon wo o pe niwon igba ti won ko je ko pari ijoba re akoko, o si le maa kawe re lo.

A ko nii sai ranti pe Fayose si n dun mahuru mahuru mo Fayemi. Oun ati awon ile igbimo asofin ipinle naa ni awon fe se itopinpin re, tori won ni ijoba re (Fayemi) se awon owo kan basubasu nigba ti won wa ni aleefa. Fayemi naa wa ni iro ni won pa. O tile ti fe lo si ile ejo bayii, to si fe ki ile ejo pase pe won ko gbodo se itopinpin oun. Awon amoye gbagbo pe gbogbo e, gbogbo e, tori idibo gomina to n bo lona yii naa ni. Se bi ologbon meji ba n fi obe osiki je iyan, afaimo ki omi tooro ma gbeyin ninu abo!

Oro naa lo gbe wa lo si Ipinle Ogun, nibi ti Gomina Ibikunle Amosun ti n da bi edun, to fe maa ro bi owe lori bi nnkan yoo se ri ni 2019.

Dajudaju, Amosun mo ibi to n lo. O ni nnkan to fe se lokan. Bi erongba re yoo wa ba ti awon egbe APC ati ara ilu mu ni ko tii ye eniyan.

Lona kinni, oun ati eekan nla fun egbe APC, Asiwaju Bola Tinubu, ko gba ti ara won. Ore oju meji ni won ti n ba ara won se lati igba ti Buhari ti de ijoba. Bee naa ni Fayemi ati Minisita fun oro Agbara ati Ile Gbigbe, Ogbeni Babatunde Fashola. Anjuwon wa laarin won – anjuwon ti ko tan lejo, ija ilara ko tan boro. Koda, awon amoye ni gbogbo bi aarin Buhari ko ti dan moran to, awon atilaawi mo si i. O si wa jo gate, ko jo gate, o fese mejeeji tiro!

Eni kan ti a gbo pe Tinbu fara mo lati dije fun ipo gomina ni Ogun ni Senito Olamilekan … Yayi. Oun naa si ti bere eto, ojo pe die. A gbo pe o ti n desa okete laarin awon oloselu nla nla ati lobaloba, nijoyr nijoye. Okunrin naa lowo lowo die, o si ti n na an.

Gbogbo gulegule yii ni Amosun mo si, ti oun naa si n ja fitafita lati ri i pe oun ni oun fa asoju kale fun APC. Lara won oun ti Amosun n se ni fifa oju awon oloselu kan mora. O tun n fa oju awon eniyan mora nipa pipada si idi awon ise kongila ti won ti pati tele. Lara won ni biriiji Alagbole ati ona Magboro.

Sugbon ibi to jo pe agbara re po si ni Abuja, nibi ti o ti gbagbo pe iranlowo yoo sele fun oun ti oko ba de oju agbami. Nje yoo see se fun Amosun bi?

Owo Olorun ni idahun si eyi wa. Sugbon awon eniyan kan naa sa pamo si Ogun to je pe orisa akunlebo ni awon naa. Lara won ni OloyeOlusegun Obasanjo, ti opo n pe ni Ebora Owu; Oloye Olusegun Osoba, ti oun naa ni ero tie leyin; Otunba Gbenga Daniel, Ogidi Omo; ati Oloye Buruji Kashamu, ti o maa n na owo fun oselu pupo.

Laarin awon ipinle ile Yoruba, Ondo ati Eko nikan ni ariwo ko tin ii po pupo ju ni 2019. Lona kinni, Arakunrin Rotimi Akeredolu sese gba opa ase i. Ko ni si idibo ni Ondo.

Ni ti Ogbeni Akinwunmi Ambode, boya  ni alatako kankan le wa, tori aimoye eniyan lo setan lati dibo fun un, latari aseyori alailegbe to ti ni. Gomina naa ni itesiwaju Ipinle Eko lo je oun logun. O si ti mu itesiwaju naa ba Eko. Eyi tumo sip e, e ma ba mi du u, nnkan mi ni ni orin ti yoo gbode kan ni Eko Akete ni 2019.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…