Home iroyin Owo te ogbologbo Ajinigbe
iroyin - June 14, 2017

Owo te ogbologbo Ajinigbe

Yoruba bo, won ni  “Ojo gbogbo ni t’ole. Ojo kan ni t’olohun”. Ogbeni Chukwudidumeme Onuamadike ti gbogbo eniyan mo si Evans ni owo sinkun awon olopaa te ni ilu Eko.

Evans gbona janjan nibi ise ajinigbe, won ni foonu alagbeka re to mokanla, o si ni bi o se maa n dari okookan fun awon adugbo kookan. Nomba to n lo fun ise ibi ipinle Eko ko ni o n lo fun Anambra, eyi to n lo fun Rivers ko ni o n lo fun Kaduna ati bee bee lo.

Arakunrin yii ko tii ju omo odun merindinlogoji lo, o daju de bii wi pe, o le gbe eniyan pamo fun osu mefa si meje titi ti ebi awon to ji gbe fi maa san owo won. Evans o ki n se ise kee-kee-ke, awon ise to lowo nla-nla lo maa n se. Awon ise bii oodunrun tabi irinwo milionu naira ni awon ise to maa n se. Opo awon olugbe adugbo bii Festac, Amuwo Odofin ati awon adugbo miran ni won ti sa kuro nitori re. Opo tile file sile lai gba enikankan sii titi di oni nitori iberu Evans.

Mogodo to wa lara awon adugbo towo re won ju ni Naijiria ni Evans ko ile bii aafin oba si. Bi o se ni ile ati dukia ni orileede yii naa ni o ni si oke okun.

Ti ina ko ba ni alawo, ko le goke odo. Evans ti bere si ni daruko awon ti won jo n sise ibi naa ati awon baba isale re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…