Home Orisirisi Iyán ogún ọdún
Orisirisi - June 14, 2017

Iyán ogún ọdún

 

Oro agba, bi ko se lowuro, a se dandan  ni ojo ale. Odun kerinlelogun niyi ti gbogbo ile ati ona dibo fun oloogbe Moshood Kashimaawo Abiola gege bi Aare Naijiria.

Igba akoko si ni iru ibo bee maa waye ni orileede wa, ibo naa ko ni nnkan se pelu elesin-mesin tabi eleya-meya. Alagba Babagana Kingibe ni igbakeji Abiola nigba naa, awon mejeeji je elesin Musulumi. Gbogbo omo Naijiria si dibo fun won.

Ibrahim Babangida ni Aare ologun ni igba naa to fagi le ibo to lo ni irowo irose ju lati igba ti Naijiria ti bere. Abajade ote ibo, iwode ibo naa lo mu emi Abiola, iyawo re pelu opo eniyan ni asiko naa.

Yoruba bo won ni “iyan ogun odun, a maa jo ni lowo”. Gbogbo awon to lowo ninu fifa igi le ibo naa ni ara n ni lati igba naa. Babangida to je olori awon olote igba naa soro laaaro yi pe, awon omo Yoruba to loruko naa lo wa nidii oro naa, o ni ti oun ba ni ki oun maa daruko won, nnkan a baje. Nitori pe awon ti a ko le lero ni won wa nidii oro naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…