Àwọn Ihenacho gbá bọ́ọ̀lù bí ẹni ẹyin fọ́ mọ́ nínú
Egbe agbaboolu Super Eagles ba okan opo awon ololufe won je ni irole oni (Satide) nigba ti won gba akegbe won lati South Africa, iyen Bafana Bafana,laye lati na won ni anabole.
Goolu meji ototo ni Bafana Bafana gba wo inu awon Super Eagles, ti won si n wo duu, laile da okan soso pada, ninu idije naa to je okan lara igbaradi fun Nations Cup to n bo.
Nipa bee, Bafana Bafana fi ye won pe loooto ni aileja ni ita baba mi ko de ibi, tori ilu Uyo, ni Ipinle Akwa Ibom, ni won ti gba boolu naa.
O ya opo eniyan lenu pe awon agbaboolu ti Naijiria gbemi le, bii Alex Iwobi to n gba boolu fun Arsenal ati Iheanacho, to n gba fun Manchester United, ko ri nnkan gidi kan se.
Bi won ba ti gbe boolu de iwaju, won kan n se ese tuetue ni, ti won n se ese bii ti tata.
Opo eniyan lo n fi won se yeye pe bi South Africa ko ba mu golikipa wa gan-an, Super Eagles ko ni le gba boolu kankan wole.
Pelu ohun to sele, won tun fi okuta se adari won, iyen Coach Genrot Rohr, lowo, tori okele akobu re ti rahun obe bayii.
Genrot Rohr
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…