Home LÁGBO ÀRÍYÁ Iro ni won pa mo mi, emi kii mu siga – Bimbo Akintola
LÁGBO ÀRÍYÁ - April 26, 2017

Iro ni won pa mo mi, emi kii mu siga – Bimbo Akintola

Osere tiata pataki kan, Bimbo Akintola, ti so pe iron la ni awon to so pe oun maa n mu siga n pa mo oun.
O ni opo igba ni won ti maa n so bee, to si je pe won ko ka siga eyo kan mo oun lenu ri.
Arabinrin naa to ti kopa ninu opo fiimu Oyinbo ati ti Yoruba so pe un mo pe ewu nla lo wa ninu ki eniyan maa mu siga; nitori naa, oun kii dan an lasa wo.
O ni ko je ohun tuntun loju un mo pe ojoojumo ni awon aniyan maa n so oro aheso lori awon gbajumo.
Ninu iforowanilenuwo kan pelu awon oniroyin, Akintola so pe kii se ohun to dara ki awon obi ati ara ilu maa ko wahala le awon obinrin ti ko bat ii lo sile oko laya.
Oun naa ti le ni eni ogoji odun, sugbon ko tii se igbeyawo.
O salaye pe nigba ti won ba n ti obinrin gbon-on-gbon-on, iru awon eni bee maa n fi ikanju la obe to gbona, to si je pe o maa n bo won lenu ni.
O ni eyi wa lara idi ti opo igbeyawo kii fi ju osu mefa lo lode oni ti won fi n tu ka.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…