Home òpómúléró Idanwo nla ni igbejo Babachir Lawal je fun Osinbajo

Idanwo nla ni igbejo Babachir Lawal je fun Osinbajo

Bi ogun ba je lo, ogbon lo maa n je bo nigbeyin.
Eyi ri bee ninu oro Akowe Agba fun Ijoba Apapo, Arakunrin Babachir Lawal, ti Aare Muhammadu Buhari ti so pe ko lo gbe ile re fungba kan na.
Eyi waye latari esun owo kikoje ti won fi kan an.
Ki gudugbe to ja mo o lowo, Lawal wa lara awon to je gaba le awon eniyan yoku lori ninu ijoba Buhari.
Koda, a gbo pe won maa n gun Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo, gaagaa, ti won si n fi oju oloore awon agbaagba miiran bii Asiwaju Bola Tinubu ati iyawo Aare gan-an, Aisha Buhari, gbole.
Sugbon bayii, Osinbajo gan-an ni Buhari fi se olori awon to n gbo ejo Lawal.
Ewo wa ni ki Osinbajo se bayii? Awon eniyan kan gba pe oro naa da bii pee san fe ke. Won ni asiko niyi lati fihan Lawal pe igberaga nii siwaju iparun.
Bee, awon kan wo o pe bi komiti to n gbejo re ba se aidaa fun un, awon eniyan re to si wa ni ijoba le fi ogbon gbe ija ko Osinbajo loju.
Bakan naa, awon onwoye kan so pe bi Osinbajo ko ba fi igboya yanju oro naa, o le se akoba fun ife ti awon omo orile ede yii ni fun un.
Nje oro naa ko wa da bii amukuru to ba le ni ni epon bayii?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…