Home òpómúléró Ibo gomina Ekiti: Eefin tun n ru laarin Fayose, Fayemi, Ojudu ati Oni

Ibo gomina Ekiti: Eefin tun n ru laarin Fayose, Fayemi, Ojudu ati Oni

Eto idibo gomina n kanlekun gbogbon ni Ipinle Ekiti. Oro naa, aipe yii ni yoo da bii ojo to su dede, ti eni kan ko le mo ibi ti yoo ro si.

Lona kinni, oro naa yo da surutu sile laarin egbe PDP ati APC.

Bi o tile je pe egbe PDP ni wahala nla ni orile-ede yii lapapo, eyi ti a n pe ni national, egbe oselu naa si rese wale ni Ipinle Ekiti.

Bakan naa, Gomina Ayodele Fayose je agutan nla kan to leni leyin, to le se bee ko pa obo.

Pelu bi o se maa n ba awon mekunnnu, talaka-talakawa se wole-wode, o jo pe won ti jo mo owo ara won.

Bi Fayose se n ba won je agbado ni titi, lo n ba won ta ata rodo ati tatase, lo si n ba won gun okada kaakiri ilu.

Eyi je ki awon onwoye maa ro pe tipatipa ti a fi maa n bo ewu alabahun ni egbe APC fi le ja Ekiti gba lowo Fayose.

Sugbon awon eniyan kan ti so pe eni kan ko le tii so ohun ti yoo sele.

Won ni Fayose kan le maa ba awon eniyan yii se wole-wode, ko jo pe o ni aseyori pupo.

Koda, won n se afiwe ijoba re pelu ti ijoba Gomina Akinwunmi Ambode ni Ipinle Eko, nibi ti awon aseyori nla nla ti foju han.

Bakan naa, won woye pe wahala to ba PDP ni apapo le se akoba fun Fayose. Se bi oode ko dun, bi igbe nilu ri. Bee, oro kanle kan baale, yoo kan jeje mi ni mo jokoo mi naa.

Ni bayii, eni kan ko mo ohun ti yoo sele si egbe PDP, tori ija agba ti won n ja ti di isu ata yan-an yan-an.

Bi PDP ba se bee, to ba tuka, se awon aniyan yoo tele Fayose lo sinu egbe miiran ni?

Ohun to tun le se akoba fun PDP ni pe egbe APC lo wa ni ijoba.

Won si le lo agbara ijoba apapo, eyi ti awon oloyinbo n pe ni federal might, lati koju Fayose ati awon eniyan re si oorun ale.

Bi oro naa se sun kana won to fe dije fun ipo Gomina ninu APC niyen.

Lodo tiwon naa, adie ba lokun, ara ko ro okun, ara ko ro adie ni.

Laarin awon agbaagba oselu ibe, onikaluku lo n ro oko sodo ara re.

IROYIN OWURO gbo pe, lokan awon eniyan bii Senito Babafemi Ojudu, Dokita Kayode Fayemi ati Oloye Segun Oni, awon naa fe dije gomina.

Ojudu ko tie fi tie bo. Bo se n lo soke, to n lo sodo, ona ati ri i pe kinni naa ja mo oun lowo ni.

Oni ti se gomina tele, Fayemi naa si ti se. Won ti jo mo apade ati alude ijoba; won ti jo to kinni ohun wo, ti won si mo pe oyin ni.

Idi niyi ti awon onwoye fi n so won lowo, so won lese, ti won si n wo enu won lori ohun ti won fe so lori ibo gomina naa.

Nje ta wa ni o seese ki kinni naa ja mo lowo laarin awon meteeta? Oro naa du hun-un.

Ibi ti ibeere wa ju ni tani Aare Muhammadu Buhari yoo fe fara mo? Ta ni Asiwaju Bola Tinubu naa yoo fe se atileyin fun?

Awon omoran tii mo oyun igbin ninu ikarahun a fe ro pe ti Fayemi ni Buhari yoo se, ti Tinubu si le se ti Ojodu tabi Oni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…