Home LÁGBO ÀRÍYÁ WASIU AYINDE @60: Ó ní, ‘Mó máa ń ka orin Ayinde Barrister bí ẹní ka ìwé ni’
LÁGBO ÀRÍYÁ - Orisirisi - March 5, 2017

WASIU AYINDE @60: Ó ní, ‘Mó máa ń ka orin Ayinde Barrister bí ẹní ka ìwé ni’

Ayinde Marshal gbe ile re to wa l’Ekoo fun ijo Musulumi
Arijiyanjiyan lori awo orin K1 to dun ju
 
Ayo ati idunnu nla lo joba lokan akorin fuji pataki, Wasiu Ayinde Marshal, bayii, latari ayeye ogota odun to n se.
Ojo Jimoo to lo ni Ayinde Marshal pe ogota odun loke eepe, ti opo eniyan si n ba a se ajoyo.
Wasiu ni oro aye oun ati bi oun se di irawo nla laarin awon olorin, ori lo se e fun oun.
O ni oun gba pe oriire ati oju rere Olorun ni oun ba pade, ati pe oun ko mo o se ju awon egbe oun lo.
Wasiu ni opo awon to lopolo pipe, ti won si ni ebun,  ni awon jo bere, ti awon si se akitiyan ati goke agba, ki won di ilumoka, sugbon ti won ko di ogunnna gbongbo bii toun.
O ni idi niyi ti oun fi so pe oun kan ni oriire ni, oun ko mo o se ju egbe oun lo.
Nigba to tun n soro lori bi o se bere ise fuji, Wasiu ni Isale Eko, Lagos Island, titi de Idumagbo ni oun ti bere.
Omo Ijebu ni Wasiu loooto, sugbon ilu Eko ni won bi i si.
Ibe naa lo si ti dagba.
Wasiu salaye pe lati omo odun mefa ni oun ti n ba awon ajisaari jade, ti oun si darapo mo Sikiru Ayinde Barrister Agbajelola lasiko naa.
O ni oun tele Barrister gan-an, tori Barrister da bi angeli oun nidii ise orin.
O ni oun fi ara bale ko eko lara Barrister.
O ni oun sun mo o bi ike titi di igba to ku.
O ni awon jo maa n sun ninu yara kan naa ni nigba ti oun sese bere, to si je pe oun maa n ka Barrister bi eni ka iwe ni.
Lara eto ayeye ojo ibi re, Wasiu ti  lo se abewo si ile awon omo alai-lobii, to si fun won ni ebun repete.
Bakan naa, o fi ile re to ko si ilu Eko fun ijo Musulumi kan to da sile ni odun die seyin.
O ni ki won maa lo gege bii Mosalasi ati ibi ti won yoo ti maa seto pataki pataki.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…