Home ÀRÒJINLẸ̀ ỌBASANJỌ sọ ìtàn Bàbá Àlí, ògbójú ọlọ́sà tí wọ́n jọ pàdé lẹ́wọ̀n

ỌBASANJỌ sọ ìtàn Bàbá Àlí, ògbójú ọlọ́sà tí wọ́n jọ pàdé lẹ́wọ̀n

O so itan Baba Ali, ogboju olosa ti won jo pade lewon
Obasanjo pe ogorin odun laye, o ronu jinle lori igbesi aye re
 
 
 
Gege bi Olori Orile-ede Naijiria tele, Oloye Olusegun Obasanjo, se di eni ogorin odun bayii, o ti n se ironujinle lori igbesi aye re.
Baba naa so gbangba-gbangba pe bi oun se n ro nipa ibi ti won bi oun si, awon obi to bi oun ati bi oun se wa goke agba ti oun di Aare Naijiria leemeji otooto, oun ko lee sai ma sope fun Oluwa.
Obasanjo ni abule ti won bi oun si, iyen Ibogun, ni Ipinle Ogun, je eyi ti ko loruko rara, to si je pe titi ko wo ibe nigba naa.
O ni awon obi oun talakaawa, to je pe Olorun lo n je ki ounje osan le ti aaro ba.
O ni sugbon sibesibe, oun ma di ilumomika, ti oun di eni aye n wari fun kaakiri agbaye.
Ninu awon arokan ti Obasanjo ti wa n se, itan to so nipa ogboju ole kan je eyi to ye ko ko eniyan logbon gidi.
Obasanjo ba adigunjale naa ti oruko re n je Baba Ali pade nigba ti alakatakiti Sanni Abacha ju u si ewon.
Obasanjo ni oun woye pe okunrin Hausa naa maa n rin koja yara oun ninu ewon.
Kii se pe o fe jale nibe o, tori won ti sa oun naa mo ewon nigba naa.
O ni oun wa pe Baba Ali lojo kan, pe oun fe ki awon jo soro.
Nigba naa, Obasanjo naa ti sun mo Jesu, to ti di atunbi; se oye ni yoo kilo fun onitobi. Ebi ni yoo soro fun ole.
Aare ana naa wa so fun Baba Alli pe ki oun naa sun mo Olorun, ko ko ese sile.
Sugbon Baba Ali yari. O ni Olorun ko le dari jin oun mo, tori ese ti oun se tip o ju.
O ni oun ti pa ainiye eniyan, ki Obasanjo fi oun sile sine ese oun.
Sugbon Obasanjo ko fi sile.
O se akawe fun un pe ninu Bibeli, Mose je eni to ti pa opo eniyan, sugbon Olorun si tun lo o gege bii eni to ko awon omo Isreal jade kuro ninu ajaga Egypt.
O tun se akawe ti Dafiidi fun, eni ti oun naa ti pa ogunlogo eniyan, sugbon ti Olorun pe ni ore oun timotimo, eni ti okan Oun ko le e fi sile.
Ka ma fa oro gun, bayii ni Baba Ali ma se fi okan re fun Jesu.
Obasanjo wa so lojo Jimoo to lo pe, “Bi mo se n ba yin soro yii, oniwaasu agba (Senior Pastor) ni Baba Ali je ni Kaduna.”
Aare ana naa salaye pe iro ni Abacha we mo oun lese nigba naa.
O ni o fe pa oun ni.
O salaye pe nigba ti won so pe oun fe da oju ijoba Abacha de, oun koko ro pe won se asise, ti won si oun mu ni.
Sugbon nigba ti won ni ki oun doju ko ejo ologun (court martial), won gbe okunrin kan jade to pe oruko ara re ni Oladele.
Oladele so pe oun ati Obasanjo ni awon jo n gbimo po lati da oju ijiba Abacha bole.
Koda, o ni ninu oko Obasanjo, iyen Obasanjo Farm, ni awon ti se ipade!
“Bee, laye mi, n ko foju kan okunrin naa ri tele. Igbeyin-gbeyin ni mo gbo pe won fija je okunrin naa sodi ki o le paro mo mi ni, eyi ti awon oloyinbo n pe ni torture,” Obasanjo lo so bee.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…