Home Orisirisi Lai Mohammed kominú lórí ìròyìn ayédèrú, Ó ní wàhálà tó ń dá sílẹ̀ ju ti àwọn alákatakítí lọ
Orisirisi - Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - February 26, 2017

Lai Mohammed kominú lórí ìròyìn ayédèrú, Ó ní wàhálà tó ń dá sílẹ̀ ju ti àwọn alákatakítí lọ

Minisita fun Oro Iroyin ati Asa lorile-ede yii, Alhaji Lai Mohammed, ti kominu lori ayederu iroyin ti awon eniyan kan maa n gbe kaakiri.
Sugbon sa o, kii se IROYIN OWURO ni minisita n ba wi.
Alhaji Mohammed so pe ki eniyan maa gbe iroyin ti kii se otito, ki o maa mu atamo mo atamo, buru ju ise laabi ti awon alakatakiti ajajagbara n se lo.
O so eyi ni ilu Abuja lose to lo, lasiko ti won n se idanilekoo awon akekojade ti National Defence
College.
O ni o je ohun to dunni lokan pe opo dukuu, ogun ati darudapo lo maa n bere pelu oro enu ati ayederu iroyin.
Alhaji Mohammed se apejuwe bi awon kan se so pe Asiwaju Bola Tinubu ati Oloye Bisi Akande ko lo ri Aare Muhammadu Buhari, leyin ti o ti han si gbogbo aye pe won lo ri i.
Bakan naa, o ni awon alayonuso tun so pe Aare Orile-ede Amerika, Ogbeni Donald Trump, ko ba Buhari soro, debi pe ijoba Amerika ni lati so pe loooto ni awon olori naa soro lori telifoonu.
Minisita wa ro awon ologun ile Naijiria ki won wa ona lati wa awon to ni imo daadaa lati di opo ero ayelujara social media won mu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…