Home ERÉ ÌDÁRAYÁ Eré ìdárayá ń ran ọpọlọ pípé lọ́wọ́ – Peter Rufai
ERÉ ÌDÁRAYÁ - February 26, 2017

Eré ìdárayá ń ran ọpọlọ pípé lọ́wọ́ – Peter Rufai

Ere idaraya n ran opolo pipe lowo – Peter Rufai

Peter Rufai ni aso-ojuule fun egbe agbaboolu Super Eagles fun opo odun seyin.

O ni ere idaraya dara gan an ni, yato fun pe o n pese owo fun ebi, ere idaraya tun wa lara ohun ti o maa n mu ki opolo pe daadaa. Ni aye igbakan ni awon obi maa n wo eni to ba n se ere idaraya bi eni ti ko le da inu ro. O ni eni to ba de ori papa lo maa mo itumo ohun ti oun n wi yii daadaa.

O ni ere idaraya maa n je ki eniyan lokiki rere. O tun parawo si awon obi ni ibi ere idaraya olodoodun eleekeje ti ileewe Chrisland High ti Ikeja to waye ni papa isere Agege.

Ibe naa lo ti salaye fun awon ero pe opo ni ko mo pe oun tile le lo si Fasiti, sugbon ni igba ti o to asiko re, oun ni lati te siwaju ninu eko oun ni ilu Oyinbo.

Peter Rufai ti gbogbo eniyan mo si “Dodo mayana” tun parowa si awon elegbe re to ku, ti ojo ori o le je ki won gba boolu daadaa mo, pe ki won jowo gbe ere idaraya laruge ni orileede Naijiria. Eyi keyi ninu ere idaraya, o le je ere sisa, ifo fifo, igi jiju, ile fifo, odo wiwe tabi boolu gbigba, gbogbo eyi ti a ba se tokan-tokan ninu re lo dara to si lowo lori. O ni ko si ibi to da bii ile,” bi oko rokun, rosa, o si maa  pada wa fori bale fun elebute”.

O ni gbogbo arowa ni awon ore oun to wa ni orileede Belgium ati Canada pa ki oun le duro si ilu oyinbo, sugbon oun ko jale pe “ajo o le dun titi ko’nile ma lo ile”. O ni eyi lo mu ki oun wale dandan.

 

Ike Sorunmu f’idunnu han s’awon akeeko Chrisland

Ojo keji ti awon ileewe sekondiri se idije onilejile won, ni awon alakoobere naa se tiwon ninu ogba ile-iwe won to wa ni Opebi, Ikeja ni ilu Eko. Ike Sorunmu ni alejo pataki ojo naa.

Nibi to ti n soro gege bi alejo pataki lo ti fi idunnu re han si awon oje-wewe naa bi won se n sare bi ehoro. O ni koseemase ni ere idaraya fun omode ati agba. O ni to ba seese ni ki awon ojo kookan naa maa wa fun awon oluko ati obi naa lati maa se ere idaraya tiwon naa. O ni eleyii maa n je ki eniyan ni alafia to peye, O ni yato fun ounje to dara, ere idaraya lo tun ku ti ko see  fi owo ro seyin ti eniyan ba fe gbadun aye re.

O gbe osuba fun awon akekoo obinrin ti won gbegba oroke nibi idije ologorun-un ati igba ibuso (100m & 200m JN girls). Nadra Alabi se ipo kinni, Michelle Okwuzi se ipo keji nigba ti Otto Abasi se ipo keta.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…