Home ÀKỌ̀TUN ÀÌSÍ-NÍLÉ BUHARI Láarin osù kan péré, Ọ̀ṣínbàjò gbé ògo Yorùbá yọ
ÀKỌ̀TUN - Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - February 26, 2017

ÀÌSÍ-NÍLÉ BUHARI Láarin osù kan péré, Ọ̀ṣínbàjò gbé ògo Yorùbá yọ

Adura si n lo ni pereu lori ilera Aare Buhari

 

Leyin ti Aare Muhammadu Buhari ti so gbedeke pe oun ko le tii pada si Naijiria bayii latari ayewo ilera to lo se ni orile ede United Kingdom, o ti wa ye awon omo Naijiria pe, lowolowo yii, Ojogbon Yemi Osinbajo lo wa ni ipo.

Idi niyi ti won ko fi pe e ni igbakeji aare mo; Adele Aare ni.

Igba ti Buhari ba pada si Naijiria ni Osinbajo yoo to pada si oofisi igbakeji.

Eyi si wa tumo si pe oruko re ti wo iwe itan pe o je Adele Aare (Acting President) ri.

Sugbon sa o, oro to w anile yii ki se pe a ti fi oje bo oloosa lowo, to ku baba eni ti yoo bo o.

Sibesibe, igbese ti Osinbajo ti n gbe lenu igba to debe yii ti fa ki opo eniyan si maa kan saara si i.

Kanmo-kanmo lo n se, ti ipinnu ati ise ijoba si n ya.

A gbo pe opo awon rinu-rode ti won ko je ki ise o ya Buhari, ti awon eniyan kan n pe ni cabal, naa ti sun seyin bayii, tori won rii pe omi Osinbajo tuntun ti ru, ti eja tuntun si ti wo inu re.

Gege bi olubadamoran kan fun okan lara awon minisita naa se so fun IROYIN OWURO ni bonkele, o ni awon minisita naa ti wa kun irin ese won.

O ni nigba ti won ri i pe Osinbajo kii se eni kan ti o maa n fi ise fale, awon minisita naa ti ri i pe orin ti yi, ilu ti yi. Ki owo ijo naa o yi ni.

Lenu igba ti Osinbajo di Adele Aare, o ti buwo lu awon ofin tuntun kan ti o wa lati ile igbimo asofin.

Awon bii abadofin merin ti o si ri i pe o ni konu-n-koho ninu, o da a pada fun awon amofin naa.

Awon amofin naa wa n wo o pea bi Osinbajo ti awon ti mo tele ko ni eyi ni.

O tun se ohun pataki kan lose to koja, nigba ti ijoba pase pe ki awon banki maa ta owo ile okeere lori igba.

Awon ti won n ta a tele kan maa n se ohun to wu won ni, debi pe won maa n gbowo le e.

Eyi lo fa a ti nnkan fi won gogo.

Pabambari igbese ti Osinbajo wa gbe ni pe o se abewo aisotele si papako oko ofurufu ti Eko, nibi ti jinnijinni ti da bo opo osise nibe.

Akowe Iroyin fun Osinbajo, Ogbeni Laolu Akande, so pe oga oun gbe igbese naa lati mo bi nnkan se rig an-an ni papako naa.

O ni ipinnu ijoba ni lati je ki nnkan maa lo gaara nibi ise kaakiri Naijiria.

Pelu ayipada ti Osinbajo n se yii, opo eniyan lo ti kan saara si i.

Koda, awon omo egbe PDP n yin in lawo, debi pe okan lara awon, Ogbeni Reno Omokri, fee so asojasan nipa siso pe o jo pe lati odun 2015, Nigeria sese ni Aare ni.

Ohun ti Osinbajo n se tun ran awon eniyan leti Oloye Obafemi Awolowo, eni ti opo eniyan gba pe o ni kokoro itesiwaju Naijiria lowo, sugbon ti ko ni anfaani lati de ipo aare.

E wa wo ise Olorun o: Omo Ikenne ti Awolowo ti wa ni Osinbajo je, iyawo re naa niyi, omo Awolowo ni!

Awon kan tun n so pe gbogbo aseyori ti Osinbajo ba se, Adiwaju Bola Tinubu naa gbodo gba oriyin.

Idi ni pe won ni oun lo hu u jade nigba to koko fi se komisanna ni Eko, to sit un fa a kale gege bii olubadije fun Buhari.

Gbogbo e. gbogbo e, awon omo Naijiria si fe ki Osinbajo o sise takuntakun pelu Aare Buhari nigba to ba de, ko ma so pe tori pe oga oun ti de, ko wa fa seyin.

Adua si n lo ni pereu fun Aare naa.

Bi awon Musulumi se n gbadura, ti awon elesin igbagbo n gba naa ni awon omo ile iwe tun gbadura pataki fun ilera Buhari ni Daura, lose to lo.

IROYIN OWURO naa gba a ni adura pe ayo ni Aare Buhari yoo pada sipo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…