Home iroyin Ojoojumo ni Dada onikeeke Marwa n fipa ba mi lo po – Bukunmi
iroyin - February 22, 2017

Ojoojumo ni Dada onikeeke Marwa n fipa ba mi lo po – Bukunmi

Omodebinrin kan ti oruko re n je Bukunmi ti so fun awo olopaa pe ojoojumo ni arakunrin kan ti oruko re n je Dada Azeez fi ipa ba oun lo po, nigba ti o ji oun gbe pamo.
Keeke Marwa ni Dada n wa ni adugbo Agege ni ilu Eko.
Gege bi awon olopaa se so, owo ba Dada leyin opo iwadii, leyin ti egbon Bukunmi ti fi ejo re sun pe o ti gbe aburo oun sa lo, pelu owo ajo ti oun ni ki Bukunmi lo gba wa, to je egberun lona ejidinlogota naira – N58,000.
Nigba ti owo ba Dada, oun naa bere sii ka boroboro.
O ni ololufe oun ni Bukunmi, ati pe igba ti egbon omobinrin naa, iyen Iyaafin Gbemisola, ko fun oun laye ni oun ati Bukunmi pinnu lati salo.
Sugbon Bukunmi ni Dada lo fi tipa gbe oun salo.
O ni o fipa gba ibale oun, to si je pe ojoojumo ati ibikibi to gbe oun salo lo n ba oun sun bi oruko se maa n ba ewure sun kaakiri.
Alukoro awon olopaa ni Ipinle Eko, Arabinrin Dolapo Badmus, gba awon obi nimoran pe ki won maa daabo bo awon omo won daadaa, ati pe ile ise olopaa ti gbe keesi Dada lo si oofisi olopaa to wa ni Oduduwa ni Ikeja

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…