Home iroyin Iyawo oluko yunifasiti loyun fun birikila
iroyin - February 22, 2017

Iyawo oluko yunifasiti loyun fun birikila

O ni oju omo lo pon oun debe
 
 
Orlando Owoh kare lona orun.
Ninu okan lara awon orin re, o ni ‘E get as e be, o nib o se je.’ The wise man who died at the backyard of a foolish man, iyen ni pe nigba ti ologbon eniyan ba ku si eyinkuule omugo, e get as e be, o nib o se je ni.
Abi bawo la se fe so ti arabinrin kan, Iyaafin Kafayat, to je iyawo odidi oluko kan ni ile iwe giga gagara-gagara ti a mo si Lagos State University, to je pe o ti wa di ololufe birikila kan bayii o.
Koda, Kafayat ti loyun fun birikila naa, ti a mo si Fatai Alimi.
Ere ni tisa agba naa koko pe e , nigba to gbo pe ile birikila naa ni aya oun wa.
Aseyinwa, aseyinbo, oro ti di ti kootu, ti Kafayat si so pe Fatai ni oko oun bayii, tori o ti fun oun ni ohun ti alagba Oyekunle ko le fun oun.
O ni lati odun ketala ni oun ati Oyekunle ti n womo, ti awon ko ri, leyin okan soso ti awon ti bi.
Sugbon nigba ti nnkan ti wa senu rere fun oun lodo birikila naa, oun ti dupe lowo Olorun ni toun o.
Ere ni, awada ni, ojo kejila osu kejila ni awon adajo yoo maa gbejo lori isele naa.
Hmm, e get as e be, bi orin Orlando.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…