Home Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ Buhari sọ Lọndọnu di Mẹ́kà, gbogbo ayé ló ń lọ kí i níbẹ̀
Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - February 19, 2017

Buhari sọ Lọndọnu di Mẹ́kà, gbogbo ayé ló ń lọ kí i níbẹ̀

Isinmi olojo gbooro ti Aare Muhammadu Buhari gba, to si wa ni orileede United Kingdom ti mu ki awon otookulu eniyan lo maa be e wo nibe o.
Ilu London ni Buhari ti wa lati bii osu kan, nibi to ti se ayewo ilera re, ti awon dokita si ni ko ma tii pada wa sile.
Opo eniyan lo n so orisiirisii, debi pe awon alayonuso kan ni olodi Aare ti ku.
Nigba to ya, won ni ko le e soro mo ni.
Sugbon igbeyin-gbeyin, o wa ye omo Naijiria pe ara kii sokuta ni oro Buhari, o lo fara nisinmi ni.
Eyi lo fa a ti awon eni bi eni, eeyan bi eeya se wa n lo be e wo ni London.
Lara awon eniyan pataki to koko lo ni awon olori egbe APC bii Asiwaju Bola Tinubu ati Oloye Bisi Akande.
Lose to lo, awon olori ile ilgbimo asofin ni Abuja, Dokita Bukola Saraki ati Onarebu Yakubu Dogara, naa lo be Buhari wo.
Iroyin ayo ni won mu de, ti won si so pe Olorun ti gbakoso.

…Won gboriyin fun Osinbajo lori bo se n dele de Buhari
Oloselu kan to fi Abeokuta ni Ipinle Ogun se ibujokoo, Oloye Jide Owolabi, ti se sadankaata fun Adele Aaare Orileede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo, latari ipa to ti n ko latigba ti Aare Muhammadu Buhari ti lo fara nisinmi ni ilu London.
Oloye Owolabi ni Osinbajo fihan pe awo oun ka oju ilu, tori bi awo ko ba ka oju ilu, yiya nii ya.
Nigba to n ba IROYIN OWURO soro, o ni Osinbajo ti fi ara re han gege bii eni to le da ipinnu se, ti ko si beru lati je olori.
Alagba naa ni, “O ye ki inu awa omo Yoruba o maa dun pe Ojogbon Osinbajo n gbe awon igbese to dara nigba ti Buhari ko si nile. Bi o se n sa lo soke lo n sa lo sodo. Lori oro aje, o n gbe awon igbese kan kanmo-kanmo. Lori oro alaafia ati irepo, o n se bee. Bi apeere, o ti lo se ipada po pelu awon olori Niger Delta ati Gomina Ipinle Rivers, Nyelson Nweke. Awon ami olori nla ni eyi.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…