Home iroyin Orogun owo ni ija emi ati Barrister – Kollington Ayinla
iroyin - February 19, 2017

Orogun owo ni ija emi ati Barrister – Kollington Ayinla

O tun ni iwa ole ati jibiti lo ba Naijiria je

 

Ose ti o koja ni iwe IROYIN OWURO gbo awo orin Democracy ti Oloogbe Sikiru Ayinde  Barrister. Orin yii je ki a ranti bi Barrister se yan-nan-nan oro aje wa, iye ti a n se owo Dola ti ile okere si Naira, iye ti won n ta opo ounje ni aye atijo ti a tun n pariwo. A wa wo o pe iru orin wo ni Oloogbe yii ki ba tun ko to ba wa laye pelu ibi ti oro aje wa de duro bayii. Eyi lo mu Yinka Alabi ati Arabinrin Oluwatoyin Mathnuel se abewo si ile Alhaji Rasak Ayinla Kollington ni Alagbado to wa ni ilu Eko. Kollington soro ile kun un, e je ki a jijo gbadun iforo-wani-lenu-wo naa.

Iroyin Owuro – E ku ikale sa, se ajinde ara n je?

Kollington – E kaabo o, eyin oniroyin.

Iroyin Owuro – A ku oro ilu yii.

Kollington – Oro ilu niyen, gbogbo wa la o se aseye nibe.

Iroyin Owuro – Ase. Igba wo ni ki a maa reti awo orin yin?

Kollington – Mo mo pe ohun ti e maa koko bi mi naa niyen. Eyin nikan si ko, opo eniyan naa lo n pe mi lori aago ti won si n beere nnkankan naa. Oro po ninu ibeere naa, loooto ni mo maa n da opo lohun pe ki won maa reti laipe, sugbon emi mo pe okan mi ko si nibe mo. Oro ilu yii da bii kin ni iwuri elewon to n faago sowo? Kin ni o wa ni ilu yii ti a n ko orin fun. Gbogbo nnkan lo ti polukurumusu bayii. Ko sowo, ko sounje, ko sise, ki n si to wuko pere bayii, awon oni pairesi ti gbee jade. Apa ijoba o si ka awon eniyan buruku yii. Won kan maa gbe eni to ni ise ati olutaja ko lu ara won ni.

Iroyin Owuro – Se ki a wa so pe awon oni Pairesi ni ko je ki e ko orin mo?

Kollington – Rara o, awon nikan ko, orin wo ni n ko tii ko lori oro ilu yii? Abi emi naa ko ni mo ko- e rora je’su, e rora mu’mi, fuudu ti gbowo lori. Nigba ti ilu tun rorun, mo tun ko orin pe – e je’su repete, e mu’mi repete Buhari ti kowo wole, mo ko atarodo o se ra loja mo, miliiki o se mu fun mekunnu mo ati bee bee lo. Meloo ni won n se amulo ninu re?

Iroyin Owuro – Awon kan ni lati igba ti Ayinde Barrister ti lo ibi agbaa re ni e ko ti rorin ko mo?

Kollington – Eyin naa mo pe ko si ooto kankan ninu re. Loooto ni pe ore mi timo-timo ni ni igba aye re, sugbon ko ni asepo pelu orin ti mo ba gbe jade. Barrister ko lo n ba mi satunse orin mi, oun ko lo n se inawo re, bawo lo se wa lasepo pelu orin ti mo n gbe jade.

Iroyin Owuro – Gbogbo awon ija aye igba kan peluu Barrister, se ija gidi ni abi lati ta awo orin?

Kollington – Kii se ija to denu, orogun owo lasan ni.

Iroyin Owuro – O je wi pe lati fi ta awo orin lasan ni.

Kollington – Eyin le mo eyi to ku, ohun ti emi mo ni pe emi re ko ja nitori pe a jo maa n fi oro jomi-tooro-oro nipa ilosiwaju orin fuji yii. O maa n so awon ogun to n jaa fun mi bee ni emi naa si maa n salaye temi naa fun un.

Iroyin Owuro – E ku ohun sa, se ogun tun wa fun iru eyin alagbara bayii ni?

Kollington – Ha ha ha, ogun wa, koda eyin tee jokoo yi naa maa ni ogun tiyin. Ogun owo, ogun idile ati bee bee lo lo wa. Ogun temi ni mo n ba yii yi.

Iroyin Owuro: Kin ni o sele si awon ile eja yin sa?

Kolington – Ha, oro po nibe, eyin naa mo igba ye. Ile eja Kollington lotun, ile eja kollington losi, bee si ni ero se maa n wo lati idaji titi di osan, amo gbogbo re ti run. A ta a peluu gbogbo ohun to wa nibe lati fi wo aisan ni. Mo ti koo lorin pe “Gbogbo eeyan to ba ti logun idile, bi tohun sise j’Erin lo, ko ni tete yo, gbogbo eeyan to ba ti logun idile, bo ni tohun sise j’Erin lo, ko ni tete yo, Idi oro re, Ayinde Ogun, idi oro ree o teeyan dudu fi n fa seyin, toyinbo fi n rowo mu…”

Ti o ba je pe o si wa ni boya n ba tile ti fi ise orin sile, sugbon gbogbo re ye Olorun. Ohun ti o kan maa n ya mi lenu pelu awon onise ibi nip e, bi e pa eni naa a ku, bi e ko paa, a ku. Eyin naa si maa tele eni naa ni ojo kan. Kin wa ni iwulo agbara buruku?

Iroyin Owuro – Opo orin ti won n ko lode oni ni ko ni itumo, se ko si atunse lati odo yin ni?

Kollington – Atunse ke? Asiko ni gbogbo nnkan, asiko tiwon niyen, won si gbodo loo sugbon kii se nnkan to maa lo titi aye. Olorun lo fi alubarika si i. E kan maa gbo ti awon eniyan maa so pe kin lo n ko, kin lo n wi , kin lo n lu bee nnkan a si maa dan fun oluwa re, Olorun niyen.

Iroyin Owuro – Kin ni ona abayo fun Naijiria?

Kollington: Ona abayo fun Naijiria je ohun ti a ko ki n fe gbo. Ona abayo o ju ki Olorun pa gbogbo wa run lo, ki o wa sese da awon miran sori ile yii nitori pe ese ati iwa ibaje ti po ju. Oyun inu ti won ko tii bi ti ni eje iwa ibaje ati ajebanu. Iyen tabi ki Olorun yanju awon to ti n se ijoba lati odun 1960 titi di asiko yi. Abi e ko gbo aduru owo ti ijoba Buhari ri gba lowo enikan. Owo to ye ki gbogbo wa maa fi gbadun. Eyi lo maa n faa ti awon Oyinbo se maa n fi wa se yeye, ti won se maa n fi wa we obo, awon omo oyinbo ti ko lekoo ti beere ri lowo wa ni igba ti a de ilu won pe “iru wa da” (where are your tails?) ati awon abuku miran latari ohun to n sele yii naa ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…