òpómúléró - February 19, 2017

buhari

Ti a ba ko odo mewaa jo ni orile ede yii, ti a si bi won leere pe ta ni eni awokose (iyen role model tabi source of inspiration) won, bii meje ninu won yoo daruko Alhaji Tajudeen Afolabi Adeola.
Idi nip e ojogbon Tajudeen Afolabi Adeola je onisowo to danto, to si gbajumo laaarin awon awokose ati onisowo ni ile yi.
Lati ile-iwe girama Eko Boys High School, ni ipinle Eko lo ti n gbayi bo. Ni ile-iwe Yabatech gan-an gege bi akeko,  o gbayi o gbeye ko to jade pelu ami eye to gagara.
Leyin igba ti to ti kawe gboye tan, ti o si ti sise pelu awon ile-ise to loruko nile yii ati loke okun, o wa pawopo pelu Oloogbe Tayo Aderinokun lati da ile ifowopamo GTBank sile.
Ile ise yii di ikan gboogi ninu awon ile ifowopamo, ti opolopo awon eeyan sii n kan saara si i bi ile ise yii se n tuko eto ifopawopamo.
Ile-ise yii gbooro de bi pe o bere si ni eka kaakiri gbogbo ile Adulawo Afrika ati ilu-oba.
Odidi odun mejila ni Fola Adeola fi tuko ile ifowopamo yii gege bi alase ati oludari, ni 2002 ni o feyin ti, Aderinokun sib ere sib a ise lo nibi to fi si.
Aseyori alailegbe yii ni awon oloselu ri ti won fi pe Fola Adeola lati wa kopa gege bii igbakeji Aare fun orile-ede Naijiria ninu eto idibo 2011 ninu egbe ACN.
Fola Adeola je eni to see fokan tan ati olooto eeyan. Idi niyi ti awon ti won wa ninu egbe ACN ri i daju pe oun gan-an ni won mu gege bi igbakeji Aare fun Nuhu Ribadu yii.
Gegebi ogbontarigi onisowo ti ile-ise re n gbooro, se ni Fola tun wa gbiyanju  lati mu iderun ati idekun ba awon mekunnu, idi niyi ti o fi da ajo FATE Foundation sile, ti o n ko awon odo ni ona idagbasoke, sise oludari ati ise okoowo, o si n ran awon odo lowo lati goke agba ninu okoowo won.
Lakootan, opomulero to je eekan ni Fola Adeola je ninu awon omo ile Yoruba lagbaaye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…