Lai Mohammed dojú kọ igbó Sambisa
KÌÍ BÁ NI KÁ ẸRÍ:
Lai Mohammed dojú kọ igbó Sambisa
.Ezekwezili ní Sambisa tóbi tó Ìpínlẹ̀ Eko lọ́nà méjìdínlógún
Gege bii awon akoni meje to lo sinu Igbo Olodumare ninu iwe DO FAGUNWA ti akole re n je ‘Ogboju Ode ninu Igbo Irunmole’,
Minisita fun Oro Iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed, se abewo nla si inu Igbo Sambisa, ni Ipinle Bornu, lose to koja.
Inu igbo alai-latopin naa ni awon alakatakiti Boko Haram sa pamo si, ti won si n tibe da awon soja Naijeria ati awon eniyan loro.
Teletele ko si eni to le sun mo igbo naa, latari bi awon Boko Haram se n jaye alabaka nibe.
Inu igbo naa ni a gbo pe won ko awon omo Chibok Girls si, iyen awon onobinrin ile iwe ti won ji gbe lo.
Sugbon nigba ti Buhari dori aleefa awon soja Naijiria ti gba agbara sii.
Won doju ija nla ko awon Boko Haram, debi pe won lo kogun ba won ni Sambisa.
Leyin ti Sambisa bo sowo Naijiria tan ni awon ajajagbara fun awon omo Chibok Girls to ku so pe o di dandan ki ijoba wa awon omo naa lo sinu Igbo naa.
Ede aiyede koko waye nigba ti awon ajajagbara naa ti a mo si Bring Back our Girls Group so pe awon naa fe lo sinu Igbo naa.
Ni igbeyin gbeyin ijoba apapo gba lati mu lo lara awon eniyan naa.
Lara awon to lo ni Alhaji Lai Mohammed ati Iyaafin Oby Ezekwezili, to je oga awon ajajagbara naa ati awon oga ologun.
Nigba ti won de, won royin ohun ti oju won ri lohun-un.
Inu minisita naa dun pe awon loo re, awon si bo layo.
O ni irinajo naa fihan pe loooto ni pe Sambisa ti bo si Naijiria lowo pada.
Ni ti Ezekwezili, o ni igbo Sambisa tobi debi pe titobi re to Ipinle Eko ni ilopo mejidinlogun.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…