Home òpómúléró OLOYE MICHAEL ADE-OJO: Ẹni ńlá tíí ṣe ohun ńlá…
òpómúléró - February 19, 2017

OLOYE MICHAEL ADE-OJO: Ẹni ńlá tíí ṣe ohun ńlá…

Ti a ba n soro nipa omo Oodua atata, ti o te pa mose ti o si see fokan tan, ti o ti ran tonile telemu lowo pelu dida ile ise sile, okan gbogi ni Oloye Michael Ade Ojo. Oloye Michael Ade Ojo ni ojo kerinla osu kefa odun 1938 ni ilu Ilara-Mokin , ni ipinle Ondo. Ilu ilara ni baba ti lo si ile iwe alako bere won to lo si Imade College ni ilu Owo labe idari baba Adekunle Ajasin laarin 1954 si 1958 lati igba naa ni baba yii ko ti duro iwe kika mo. Osu mejidinlogun ni Michael fi kawe ni ile-iwe eko agbe ni Akure, ki baba to di ero Usukka fun eko yunifasiti ni Yunifasiti tii Naijiria, UNN.

Opolopo awon ile ise nlanla ni baba ti sise, ti baba si ti fi ami akin, akinkanju, olooto, eniti-o-see-fokan-tan ati eni-to-see-gbe-emi-le han. Lara won ni CFAO ti o se agbateru odun meji ninu eto eko baba, Federal Inland Revenue Department ati British Petroleum Nigeria Limited ti o di (AP) loni.
Nigba to to odun mewa ti Michael ti jade Yunifasiti ni o tii fi ise ti o n se sile ti o si lo da ile ise tire sile pelu oluranlowo ti o jade lati inu eegun re, Elizabeth ti o je iyawo baba Michael Ade Ojo yii ni awon mejeeji jo da Elizade Independent Agencies sile. Loni ile-ise to ni osise kan pere ni odun 1971 ti di ilu mooka ile-ise to si ti bi omo repete. Elizade Independent Agencies yii bii awon ile ise miran bii Toyota Nigeria Ltd, Odua Creations Ltd, Oloye Michael Ade Ojo gan-an wa di alaga oke aimoye ile-ise nlanla ni orileeede Naijiria.

Baba feran asa ati ise awon eeyan won gan-an, won si feran ilu won de gongo, de bii pe kilomita ona to le ni mejo ni baba da oda sii ni ilu Ilara-Mokin, won da banki sile ninu iluu won ni ki awon eeyan won le maa je igbadun ile-ifowo-pamo igbalode talagboole Shield.
Mi mu idagbasoke wa si gbogbo agbegbe ti baba ba wa ni o je ki awon otokulu ati Oba maa fi oye rabande da baba lola,ninu oye ti won je ni: Aare Ataiyese ti Ilara-Mokin, Asiwaju ti Imesi-Ile, Baaloro ti Source ti Arole Oodua, Oba Okunade Sijuade, Ooni ti Ile Ife fi baba je. Akaimoye oye ni baba gba kaakiri Naijiria ati ni oke okun.Ni ojuna ati mu eto eko to peye wo ilu Naijiria ni o je ki baba tun loda da Elizade University sile, eyi yoo tun mu idagbasoke to kuna ba ilu Ilara mokin, ipinle Ondo, ati Naijira lapapo. Oloye Michael Ade Ojo je onisowo oludasile ti ko legbe, lati inu nnkan kekere ni baba ti yo oke aimoye ile-ise to ti laamilaka!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…