Home ÀRÒJINLẸ̀ Esi Ibo Amerika
ÀRÒJINLẸ̀ - February 19, 2017

Esi Ibo Amerika

Yoruba bo, won ni “oro kanle, kan baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi”. Esi ibo Orileede Amerika ti n da awuye-wuye sile kaakiri agbaaye. Ibo Aare waye ni ose to koja laarin Donald Trump ati Arabinrin Clinton. Opo eniyan paapaa julo awon alawo dudu fe ki Clinton wole nitori pe, a wi fun ni ko to dani, agbalagba ijakadi ni. Trump salaye ni ibi ipolongo ibo re pe oun ko feran awa alawo dudu rara. Eyi si mu ki inu awon alawo funfun dun pe boya ti o ba wole ibo, a le ba awon le awon alawo dudu danu.
Nigba ti esi ibo jade ti Donald Trump jawe olubori, iberu bojo ti de ba opo eniyan nile ati ni oke Okun. Gbogbo eleyii o tile jo emi loju bi ko se eebu ara ti Netanyahu to je Aare orileede Israel bu awa eya Afirika. O ni ko si boju-boju ninu ikorira ti oun ati Trump ni si ile Afirika. O ni awon o le maa dibon bi awon alawo funfun to ku. O ni idasile orileede ti awon waye pelu opolo pipe ati ise asekara.
O ni ko tumo si pe, ni igba ti emi ti wa lara gbogbo wa ti so wa di bakan naa. O ni a ju ara wa lo ti kii se ti ijakadi. O ni a ko gbodo so pe nitori pe Alangba n faya fa ti soo di bakan naa pelu Oni. O ni Olorun to da awon ni alawo funfun pelu ori pipe mo ohun to n se. O ni ti Olorun ba fe ki gbogbo wa maa ronu bakan naa ni, Ko ba ti da gbogbo eniyan ni alawo dudu. O ni ti awon alawo dudu naa ba lopolo pipe ni, kin lo de ti won ko le da nnkan gidi se? Kin lo de ti won ko le da ilu won dari? Kin lo de to je iranlowo lati oke okun ni won maa n duro de ni gbogbo igba. Ile Afirika o mo ju ariwo, ijo, ka fe iyawo repete, ka bimo lai toju, ka mu oso, ka mu aje, ka ja lai nidii, agbere sise, ole, Imotara-eni nikan, ka muti, ka dibon si Mosalasi ati Soosi bi eni Olorun. O ni loju ti oun ile Afirika da bi apeere ise ati osi.
O ni gbogbo ohun alumoni ile tii mu ki ilu lokiki lo rogun si ile Adulawo sugbon ti won ko moo lo. O ni afi ti awon alawo funfun ba to de ibe ti awon mu eyi to wulo nibe ti awon si fi rale-rale sile fun wa ti a si tun maa para wa nitori re. O ni, oun ni igbagbo pe Olorun gan an ti maa kabamo pe Oun da alawo dudu abinu dudu, elero dudu, olopolo dudu ti ko larojinle.
Oro buruku ni Prime Minister Orileede Israel so, loju temi, ogulutu lo so ti o maa ta ba ara ile ati ara oko, ti o si ye ki eni to ba ta ba o tun ara re se. Eebu ara buruku ni, abi ti kii ba se eebu ara wa, e wo iye owo ti awon alase ilu Naijiria n ko je. Se won fe maa je lai fi ra nnkan ni? E wo awon kan to n bo tiwon mo inu ile, inu tanki omi lawon kan n ko tiwon si. E wo ona Eko si Ibadan. Awon ara adugbo Mowe/Ibafo maa n fi wakati meta si merin rin de ibi ise laaaro, won a si fi wakati marun un si mefa pada ni ale. Eyi da emi ati eyin ololufe abala arojinle loju pe, alawo funfun o ni gba ki awon maa fi wakati mesan an si mewaa rin ona ninu wakati merinlelogun to wa lojumo. Ona abayo ni awon alawo funfun a koko wa ki won to bere iru ise ona pataki bee. Ona abayo bii ki won koko se awon ona ile lapa otun ati ni apa osi, won maa ri pe ina ibe mole bii osan. Won le ko moto boginni-boginni sona lati din iye moto ayokele ku lona. Won le koko se ona oju irin ki won to bere ona. Owo ti Dasuki n pin nikan se gbogbo ise yii. Aabo oro laa so fun omoluabi, to ba de inu re a dodidi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…