Home ÀRÒJINLẸ̀ Àsejù baba àsetẹ́
ÀRÒJINLẸ̀ - February 19, 2017

Àsejù baba àsetẹ́

Àsejù baba àsetẹ́

Leyin ominira ni gbogbo aye, idera lo n telee ni gbogbo orile aye. Kin lo wa de ti oro Niaijiria fi yato? Leyin ominira ni Orileede Malaysia wa mu eso ope ni odo wa, o so won di oloro. Leyin Ominira ni Singapore mura si imo ero won to si so won di olokiki lonii. Leyin ominira ni India tepele mo ero komputa to so won di olokiki bayii. Bee naa ni omo sori ni China, ni UAE, ni Japan, Denmark, Amerika ati bee bee lo.

Leyin ominira Naijiria ni awa bere adura ati aawe kikan-kikan. Igba naa ni a bere si mu oso ati aje. Igba naa ni a bere eleyameya ati elesinmesin.

Olorun kuku gbo adura wa, gbogbo iwonba ileese ti awon oyinbo ko ki a to so pe a le da duro pata ni a ti so di Soosi ati Mosalasi. Awon ile ijosin dun un ko ju ileese lo ni orileede yi.

Ara adura gbigba ni awon kan tun fi dide pe ese ni iwe die ti a n ka “Book Haram” ti gbogbo wa mo si Boko Haram. Awon yii ba tun dana sun Mosalasi ati Soosi. Won n so ado iku mora lo si ibi ti awon eniyan ba po si.

Mo ni igbagbo to po ninu Olorun, mo si mo pe “ewe kan ko le jabo lori igi lai si imo Olorun nibe”. Aseju nikan ni emi lodi si gege bi imo temi se mo. Gbogbo ohun to ba le mu ki awon kan roo wi pe bi awon ba se fi emi sofo to ni orun rere awon se maa fe to, eyi ko ba laakaye omoniyan mu.

Gbogbo ohun ti Olorun ko fe ni aseju, “eni to ba si ran ara re lowo ni oosa oke n ran lowo”. Opo akekoo ni ko mo pe o ye ki eniyan koko ka iwe ki o to wa gba adura tabi ki o gbadura tan, ki o wa ka iwe, sugbon ti ko gbodo gbadura nikan lai kawe.

Opo ni ko mo pe eniyan maa n we ni ko to jare oye. Opo ni ko wa ise mo ti o kan n gbadura owo repete. Ti a ba fe rin irinajo, o ye ki a wo taya ese moto wa gbogbo, ki a fi omi si ibi to ye ki omi wa, ki a fi epo si ibi to ye ki epo wa, eyi t’agbara o ba ka, ki a pe mekaniiki sii, leyin eyi Io kan adura.

Lenu ojo meta yii naa ni gomina ile ifowo-pamo-si apapo tele, Alhaji sanusi naa parowa si ijoba ipinle Kano, ki o je ki awon lo die ninu Mosalasi repete ti awon ni fun ileewe, ki o to di pe awon rowo ko ile-iwe miran. Sanusi rii pe awon omo onibara n po sii lojoojumo. Won ko fe lo ileewe tele, ko tun wa si ileewe to kari won.

Ki Olorun dari ji mi, opo esin wa naa ni oju aye. Olorun to lesin ko see tan je, nitori pe, Oba arinu-rode ni. Bi ilu yi se maa dara di owo emi ati eyin. A-ro-jin-le…

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…