Home ÀRÒJINLẸ̀ Aya Olóògbé
ÀRÒJINLẸ̀ - February 19, 2017

Aya Olóògbé

Ijoba Buhari labe agborun ati agbojo APC ti bere bayii lati odun kan aabo. Ni t’ile t’Olorun, ijoba yi gbiyanju. Gbogbo awon ti a ro pe won ga ju ofin lo ni ijoba naa ti fi owo sinkun ofin mu.
Gbogbo awon alagbara to ti se owo ilu maku-maku ni Buhari n fimu won fina lowo bayii. Buhari ti se ohun ti Aare kankan ko se ri. O ti ba wa mu opo agba oloselu to kowo je. O mu olopaa. O mu asobode, koda o mu adajo ti Aare kankan ko mu ri. Oun naa lo tun je ki a mo pe won maa n dogbon si eto isuna ni odoodun. Gbogbo awon ti aje iwa ibaje naa se mo lowo ni won ko rii bi nnkan ibaje, won rii bi nnkan ti kii se tuntun.

Ijoba Buhari je ki a mo pe ko si eni ti a maa fowo kan abiya re ti ko nii run. Bi jibiti se wa ninu omode lo wa ninu agba, ti o si ti gbile bi owara ojo ni orileede yii.
Aya oloogbe kuku ni Naijiria, ti oko re ku ti awon ara ile bere si ni toju, lo ba n rojo epe fun oko re pe oloriburuku re, to ba wa laye, oun ko le ri itoju bee. Aya oloogbe yii naa ni nnkan sa fere fun awon to n toju re, lo ba tun fi ekun bo enu pe ti oko oun ba wa laye ni, iya o le maa je oun bayii.
Awon omo Naijiria gbe osuba rabade-rabade fun Buhari pelu ise akoni to n se o sugbon, won n se rahun ounje, won ni “ebi kii wonu ki oro miran tun wo ibe”. Iyan ti wa ni ilu, “ebi ogaja fowo meke” ti n ba omo Naijiria poo gan an ni. Awon ara ilu ni ki ijoba ko ounje ati owo jade naa, ti ilu ba wa dero tan ki a tun wa pada maa mu awon ole ati onijibiti to ku. Awon ara ilu ni iya yii po, opo o le ran omo ni ile iwe mo, awon kan ti di onikanra nitori bi ilu se ri. Yoruba bo won ni, “afi fila perin, ojo kan naa lo maa n niyi mo”. Loooto lo dara ki a foju asebi han sugbon legbe keji naa, ki ona abayo lati kuro ninu inira oda owo naa wa.
Ko kuku si ariyanjiyan lori pe awon kan ti fi odun merindinlogun ba ilu je sugbon ona abayo ni a n fe. Ti o ba je ere oko naa ni a n reti, leyin odun kan, o ti ye ki a maa kere oko. Ki Eledua ma fi ebi pa wa, ki o ma si fi iyan ba wa ja.
Ki a tile dupe pe ijoba to wa lode oni maa n ka iwe IROYIN OWURO nitori pe bii ose meta seyin bayii la se arojinle de ona Eko si Ibadan ti ijoba apapo n se lowo. A salaye awon ona abayo to ye ki won koko se ki won tile to bere ise. Ose to koja ni a rii pe won ti se ona ile ni apa otun ti a ba n bo lati Eko si Ibadan. Eyi tumo si pe, a ni ijoba tiwa-n-tiwa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…