Home ÀKỌ̀TUN Ọmọge tó ń tọ̀ sílé rí ìwòsàn l’ọ́dọ̀ TB Joshua
ÀKỌ̀TUN - iroyin - February 19, 2017

Ọmọge tó ń tọ̀ sílé rí ìwòsàn l’ọ́dọ̀ TB Joshua

O ni, ‘Okunrin meta lo fe fe mi bayii ‘
.Opo eniyan lo si n wa iwosan lo si Synagogue

Orisirisi ise iyanu lo si n sele ni soosi Synagogue Church of All Nations, ti Prophet Temitope Joshua je oludari ati oludasile fun.
Nigba ti IROYIN OWURO se abewo si soosi naa to wa ni Ikotun ni ilu Eko, a ri i pe oniruuru eniyan lo si n da lo si ibe ti won n wa idande lori erongba tabi isoro won.
Bi apeere, lojo Jimoo to lo, a se alabapade oniruuru eniyan, ti asofin ati eni to n wa oko ofurufu, ti eleyinbo n pe ni pilot, si wa lara won.
Sugbon lara ise iyanu ti TB Joshua se laipe yii ni ti arabinrin kan ti o ni adamwo ito tito sile.
Orileede Ghana ni obinrin rogbodo naa ti wa.
Ninu ijeri kan to je, eyi ti won se atejade re lori telifisan soosi naa, olomoge naa ti oruko re n je Mary so pe o ti pe ti oun ti n to sile.
O ni ti oun ba ti sun, oun yoo la ala, ti oun yoo si tibe to sara jimba.
O ni opo eniyan to mo nipa re lo maa n fi oun se yeye.
O ni nigba ti okunrin afesona oun mo pe oun n to sile, ise lo sa fun oun.
Sugbon nigba to n dupe lowo Pastor TB Joshua, to si tun n yin Olorun logo, o ni leyin ti oun ti ri idaande, okunrin meta otooto lo fe fe oun bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…