Home iroyin Rògbòdìyàn APC: Amósùn ń p’òwe mọ́ Tinubu, Irọ́ ni wón pa, n kò fi APC sílẹ̀ – Asíwájú
iroyin - February 11, 2017

Rògbòdìyàn APC: Amósùn ń p’òwe mọ́ Tinubu, Irọ́ ni wón pa, n kò fi APC sílẹ̀ – Asíwájú

Ti eni kan ba so pe ko si ija laarin Gomina Ipinle Ogun, Senito Ibikunle Amosun, ati Asiwaju Bola Tinubu, to je olori egbe APC, iron la ni oluware n pa o.
Awon amoye mo pe latigba ti Buhari ti gori aleefa ni Amosun ti sa pamo si abe re, tori won ti mo ara won tele, ki ibo to de.
A gbo pe ara ohun to da dukuu sile laarin Buhari ati Tinubu ni eyi.
Oro aawo oselu laarin Amosun ati Tinubu tun wa le sii nigba ti okan lara awon Senito to sun mo Tinubu daadaa, Olamilekan Yayi, fi ero re han pe oun fe di gomina ni Ogun.
Bee, Amosun naa ni eni to fe fa kale lokan.
Lose to lo, Amosun so oro nla kan to jo pe o fit a si Tinubu ni.
O ni oun kop e ara oun ni asiwaju ike Yoruba, sugbon oun je eni to n fi otito ba egbe APC lo, lai setann kankan.
Awon awoye waa wo o pe Tinubu lo n pa owe mo, tori awon kan ti ni ife ti Asiwaju ni si egbe APC ko fi bee gbona mo.
Koda, won ni oun ati awon oloselu nla miiran gege bii Atiku Abubakar ti n pete lati da egbe oselu miiran sile.
Sugbon sa o, bi o tile je pe Tinubu ko tii fesi lori owe ti Amosun n pa, Asiwaju Tinubu ti so pe aheso oro lasan nip e oun ti fe fi egbe APC sile.
Dipo bee, o ni oun si wa nibe digbi, tori oun wa lara awon to sise takuntakun, ti oun nawo nara lati da egbe naa sile.
Leyin Senito Amosun, a gbo pea won minisita Yoruba bii Dokita Kayode Fayemi ati Babatunde Raji Fashola ti keyin si Tinubu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…