Home Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ Ẹ̀ẹ̀mejìlá ọ̀tọ̀tọ̀ ni wọ́n ti parọ́ ikú mọ́ mi – Ọbasanjọ
Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - February 11, 2017

Ẹ̀ẹ̀mejìlá ọ̀tọ̀tọ̀ ni wọ́n ti parọ́ ikú mọ́ mi – Ọbasanjọ

Aare ijerin, Oloye Olusegun Obasanjo, ti so pe eemejila ototo ni awon eni ibi kan ti paro iku mo oun.
O ni oun a wa laye, oun a si wa laaye, won a si maa so aheso pe oun ti ku.
O so eyi nigba ti o n kilo fun awon omo Naijiria pe ki won ye ro iku ro Aare Muhammadu Buhari.
O ni ika ni awon eniyan to n ro ero laabi naa.
Gege bi Obasanjo se so ninu atejade kan ti akowe iroyin re gbe jade ni Abeokuta, o ni bi o ba tie je pe ailera kankan mu olori Naijiria, adura lo ye ki awon eniyan maa gba fun un ki ara re le tete gbe pepe.
O ni eni ti ori re ba pe ko gbodo maa gbadura ki agbalagba ku, niwon igba ti olojo ko baa ti ranse de.
Obasanjo wa fi kun un pe enikeni ti ko ba wa fe Buhari nipo mo gbodo duro di odun 2019 ko to le se ayipada.
Bayii, titi di opin ose to lo, opo eniyan lo n reti Aare Buhari pada ni Naijiria, leyin isinmi olojo mewaa ti o lo se ni orile ede United Kingdom.
Olude ti Aare gba naa lo fa a ti awon alaheso fi n so pe igba segba, awo s’awo.
Awon ololufe aaare wa gba pe bi o ba ti de lose yii, o je pe ologinni t’ajo de ni, ekute ile e para mo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…