Home Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ Buhari da ijaya si Naijiria
Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - December 23, 2015

Buhari da ijaya si Naijiria

Yoruba bo, “won ni eni to rajo ti ko tete de lo je ki aye o roku roo”. Oro yii lo se mo Aare Buhari lara. Okan awon ara ile ati ara oko ko bale lori ailera Buhari. “Gbogbo alangba lo kuku danu dele, a ko mo eyi ti inu n run” ni ise ti awon eniyan fi n jara para lori Buhari.

Awon eniyan n pe legbe-legbe, won n pe logba-logba lati fi imu finle lori ohun to sele gan-an ti Aare fi ye ojo to ye ko de. Ojo Aje, ojo kefa osu yii lo ye ki baalu Aare gunle si papako ofurufu Naijiria, sugbon kaka ki o ri bee, iroyin miran lo te omo Naijiria leti pe Aare ti sun ojo dide re siwaju. Ko si ni pato ojo ti o maa de gan-an. Eyi wa lara ohun to n ko omo Naijiria lominu.

Won ni enikankan o tile ba ilu soro lori ohun to n sele si Aare. Won ni to ba je ailera ni, iru ailera wo lo n se e? Omo Naijiria n ja fun eto won pe o ye ki a mo ohun to sele gan-an. Won ni ti ailera naa o ba le to bee, o ye ki Aare ba awon soro lati ilu London ni ko ba dara ju. Olorun kuku ti so aye di irorun, bi Aare ba se n soro ni ero ayelujara a maa gbe si gbogbo aye.

Awuyewuye yi naa lo kun iwode woorowo ti awon omo Naijiria se ni ojo Aje naa kaakiri orileede yii. Bi awon kan se jade pe ki ijoba gba awon lowo ise ati osi, ti gbogbo nnkan gbowo lori ti ko si tun si owo ni ilu, bee ni awon kan naa tun jade ni ojo naa pelu akole to yato “pe ti ijoba Buhari n awon n se”. Won ni to ba je ti ailera, ko si eni ti ko le sele si nitori pe ara o ki n sokuta, won ni to ba je ti owon gogo gbogbo nnkan, ilu ti baje ki Buhari o to gba ijoba lo faa. Won ni se bi awon naa n rii ninu iwe iroyin ni gbogbo igba iye ti awon eniyan ilu yii pin mo ara won lowo. Won n wo opo ninu ero telifison won bi awon kan se n ka boro-boro bi eni ti nnkan yiwo fun.

Won ni adiye Buhari n laagun, iye ni ko je ki awon ara ilu o mo. Ope ti awon eniyan da ju ni pe awon iko mejeeji yii o kolu ara won ni ti ija. Onikaluku lo woorowo ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…