Home Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ Idi ti mo fi se ere ibalopo okunrin ati okunrin – Odunlade Adekola
Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - December 8, 2015

Idi ti mo fi se ere ibalopo okunrin ati okunrin – Odunlade Adekola

won eniyan kan ti pe gbajumo osere, Odunlade Adekola, nija lori ipa to ko ninu fiimu tuntun kan ti akole re n je Daudu.
Ninu ere naa, Odunlade ni okunrin to so ara re di iyawo okunrin miiran.
Eyi ni awon oloyinbo n pe ni ‘gay’, eyi ti ijoba apapo ti fi ofin de.
Ninu ofin Naijiria, eni ti won ba okunrin ti won ba gba mu to so ara re di iyawo okunrin miiran, tabi obinrin to so arar re di oko tabi aya obinrin miiran, iyen lesbianism, yoo fie won odun merinla jura.
Ninu afitonilenuwo to ti jade lori Daudu, Odunlade se bi a ti wi, to n toju, tonu, tote, to si n ja gele mori.
Eyi lo fa a ti awon kan fi n so pe iru ipa to ko naa le fa a ki awon oluworan maa wo awokose iwa aito naa.
Sugbon nigba to n soro lori eyi, o ni kii se pe oun fe ki awon eniyan maa se ohun to sun mo ohun ti awon baba nla wa maa n pe ni soko-sobo nijoun.
O ni gege bii osere, ipa to ba w anile ni oun maa ko, to si je pe tiata tabi fiimu kii se ohun to n sele loju aye.
Bakan naa, o ni ti awon eniyan ba wo fiimu naa daadaa, won yoo rip e eko to wa nibe ni pe  a ko gbodo maa se nnkan ti yoo sun awon elomiran de idi ki okunrin maa so ara re di iyawo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…