Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Iyán ogún ọdún: Mọ́remí díjà sílẹ̀ láarin Ọ̀ọ̀ni àti Olúgbó
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - September 17, 2015

Iyán ogún ọdún: Mọ́remí díjà sílẹ̀ láarin Ọ̀ọ̀ni àti Olúgbó

Asiko yi je eyi ti Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, n yo ayo nla lowo.
Idi ni pe o ti pe odun kan ti o ti gori ite, to si je pe opo eniyan lo n ba a yo.
Sugbon nnkan kan si wa to n bi oba naa ninu.
Eyi ni oro kan ti Olugbo ti Ugbo ni Ipinle Ondo, Oba Onateru Akinruntan, so pe ko si nnkan kan to ye ki won maa ponle lara Moremi.
Ti e ko ba gbagbe, Moremi ni iya nla awon eniyan Ife, eni ti itan so pe o ja fitafita lati gba awon eniyan naa sile nigba ti awon ajoji godogba fe fi ogun pa won run.
Obinrin naa wuwo lokan awon eniyan Ife debi pe won si n gbe e gege bii eyin titi di oni olonii.
Won tun so opo ohun meremere loruko Moremi.
Laipe yii, Oba Ogunwusi si ere giga gogoro kan, leyii to je pe Moremi ni won ya sibe.
Sugbon, niwon igba to je pe eran aladun fun eni kan, oronro to koro ni, Olugbo ni Moremi kii se eni kan pataki to ye ki won maa gbe gege.
Eyi bi Ooni ninu, to si ni isokuso gbaa ni Olugbo n so.
Bakan naa, Ojogbon Wole Soyinka ti fi ehonu han lori ohun ti Olugbo so.
Igilango onkowe naa feran Moremi titi, debi pe o so okan lara awon omo re ni Moremi.
O ni ki Ooni ma da Olugbo lohun, ati pe ohun to ba wu elenu lo le maa fie nu re so.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…