Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Eeyan to ta ara ile e re ni po-n-to
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - February 19, 2015

Eeyan to ta ara ile e re ni po-n-to

Mo ki gbogbo ojulowo omo oko yooba kaakiri ile alawodudu ati agbegbe re, tofi dele alawo funfun ti o moyi asa,ti ki i fenu saata ise awon babanla a wa pe e ku aaye ibe,e ku idodi mu, eku u koleeda ti gbogbo wa n se,bakan naa kiki lo si odo awon eleya mi-in, ti won ko,ti won mo, ti won si n samulo asa ati ise yooba,nipa ihuwasi won, labala agbekale oro ogbon,oye,laakaye, imo to kun fofo,ti awujo fi n gbosuba funwon pe asa ati ise omoluabi mu.
Se yooba bo won ni eke daye aasa di apomu.Gbogbo oya ni n pe ara a re lodu, lorii asa ati ise ti o jo mo yooba, latari pe won ni anfaani kan tabi omi-in, bii ki won je olowo,alagbara, onipo (abbl),ti awon naa si wa tipase be e, so ara won di onpitan,tabi sorosoro, nipa asa ati ise yooba.sugbon adupe lowo awon agba ti won mo itumo o atubotan,ese mefa, pe n ti koowa o je, igo yoo pada ga ju eni ti n muti inu –un re lo ni,tori pe, iku alumuntu ,ti ko moyato laarin eru atomo,olowo ati talaka,ole si alagbara, naa ni yoo gbeyin koowa,ni a n dupe lowo o won pe, won n soju abe nikoo,fun awon eeyan ti ko mo iyato laarin owe ati ewe,ti won n jan eepo mo alikaamo,da luuru po mo sapa, ki won to maa fola jiyo, foju ola gbole ni gbagede,doju nnkan ru ,fun awon iran ti n bo.
Se yooba bo won ni eni ba so ile nu, irufe eni bee lo so apo iya ko.Bi eniyan ba si fenu saata n ti o je ti e,dajusaka ohun olohun ni yoo maa gbe ge ge ge,ey naa lo bi awon kan ti won peraawon lojulowo omo yooba sugbon ti ihuwasi won n fi gbogbo igba tako oro ti won n so.
Yooba je awujo ti o ni eto, imo-on won kun fofo,opolowo won si ji pe pe bi ewe e peregun.Sugbon o ye ki a fura bayii pe gbogbo eeyan lo ti soraawon di agbalagba bayii, se yooba si bo won ni,

o pade agbalagba lona, o ni ko gba o ni imoran, se o mo, boya radarada, wonran wonran, kebe kebe lo ba dagba. Bi ko ba ri be e, o jo be e,idi niyi, ti awon agba fi po lawujo bayii sugbon ti gbogbo nnkan si n polukurumusu mo wa lowo.
O jo pe awon alale e yooba n binu,tori pe awon eeyan kan ko mo iyato laarin esin ,asa ati ise.idi niyi ti gbogbo re fi daru ,ti ori omo tuntu fi n wo lo beere be, bi o ti le je pe awon agba lo suadada,ti won n se langbalangba,latari pe won kii sapere rere fun awujo yooba latari iwa buruku,ti o kun ikun-un won,bi i ki won o maa ba majesin sun, gbomo sowo, lu jibiti lokan o jokan,dori asa kodo ni gbogbo ona.
Bi odun tuntun ti tun n lo were were yii,mo gba a ladura pe,oduduwa atewonro yoo satunse gbogbo ibi ti oro omo alawo dudu ku si,yooba ni pato, bee , gbolohun Afonja ko ni-in won lori gbogbo odale ,sebi seka,komi esin da sile eran, pe moti moti ,ti iwo agbo o mori ni yoo mo won gege bi esan lori ihuwasi won, lori asa ati ise, ipo yoowu ti won ri ki won o wa lawujo yooba.Asa ati ise dowo ojulowo omo yooba,ire o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…