185,000 ọmọ ogun Russia ló ti bá ogun lọ ní Ukraine
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọdún 2024 tó kojá yìí ni ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Russia pàdánù ọmọ ogun tó pọ̀ jùlọ nínú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Ukraine.
Èèyàn 45,287 ni Russia pàdánù sínú ogun náà lọ́dún ọ̀hún nìkan ṣoṣo.
Iye eeyan yii lo jẹ bii ilọpo mẹta eeyan to padanu ninu ọdun akọkọ ti wọn bẹrẹ ogun naa, iye eeyan naa tun pọ ju iye to padanu ni 2023 lasiko ti ogun gbona girigi ni Bakhmut.
Nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ ogun naa, igun mejeji lo n padanu ọmọ ogun amọ nigba ti ogun ọhun n wọ ipele kan Russia bẹrẹ si n padanu ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun.
Ajọ Mediazona atawọn eeyan mii ṣe iwadii lọ iboji ti Russia n sin oku awọn ologun rẹ si, bẹẹ ni wọn tun ṣe awọn iwadii mii nipa iye eyan to ba ogun ọhun lọ.
Lọwọ yii, wọn ti ri orukọ ọmọ ogun Russia 106,745 ti wọn ti ṣubu loju ija.
Iye eeyan ọhun le pọ ju bẹẹ lọ, koda awọn onimọ sọ pe o le to ọmọ ogun 164,223 si 237,211 to ti ba ogun Russia lọ ni Ukraine.
Ogunjọ, oṣu Keji, ọdun 2024 ni Russia padanu ọmọ ogun to pọ julọ ni Ukraine.
Lara awọn to ku ni Aldar Bairov, Igor Babych ati Okhunjon Rustamov, ti wọn wa pẹlu ẹka 36th Motorised Rifle Brigade nigba ti ado oloro Ukraine balẹ siluu Volnovakha, to wa ni Donetsk.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ni ki awọn ọmọ ogun naa to sori ila fun ayẹyẹ kan ki ado oloro naa to balẹ.
Ologun marunlelọgọta lo ku lọjọ naa, ti adari wọn, Col Musaev jẹ ọkan lara wọn, yatọ si awọn to farapa yanayana.
Ẹni ọdun mejilelogun ni Bairov, to kẹkọọ nipa imọ ounjẹ ati imọtoto ayika ki wọn to ni dandan ni ko darapọ mọ awọn ologun.
Ninu oṣu keji ọdun 2022, o wa lara awọn ti wọn ko lọ si Ukraine lati lọ jagun, o si wa lara awọn to kọlu ilu Kyiv ki ilu naa to dahoro.
Iṣẹ ajorinmọrin ni Okhunjon Rustamov n ṣe ni Siberia ko to lọ soju ogun ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Ọmọ ogun mii, Igor Babych, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn funra lo yan lati darapọ mọ ileesẹ ọmọ ogun lati jagun.
Gbogbo awọn ti a darukọ wọnyii ni wọn ti ba ogun Ukraine lọ.
Lapapọ, ọmọ ogun 201 lo ku lọjọ kan ṣoṣo gẹgẹ bii abọ iwadii ṣe sọ.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Okhunjon Rustamov sọ pe mọlẹbi oun mẹta loun ti gbe sin ṣaaju ọdọkunrin naa.
Ninu ọdun kinni ti ogun naa bẹrẹ, Russia padanu ọmọ ogun 17,890.
Nigba ti yoo di ọdun 2024, iye awọn to ku goke si 37,633,
Laarin oṣu Kẹjọ si oṣu Kọkanla ọdun 2014, ọmọ ogun 1,226 lo padanu ẹmi wọn.
Nigba ti a ṣayẹwo iye awọn to ku, awọn ti wọn dawati atawọn ti a ri ikede isinku wọn, nnkan bii ọmọ ogun 21,000 si 23,500 lo ku ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2024.
Lapapọ, nnkan bii 185,000 si 260,700 ọmọ ogun Russia lo ti padanu ẹmi wọn ninu Ukraine.