Home ÀKỌ̀TUN Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 22, 2022

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ọrẹ Òtítọ́jù

À fi kí Ọlọ́run máa túbọ̀ fi àànú rẹ̀ gbà wá nínú ìrìnàjò wa gbogbo.
Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kìn-ín-ní, ọdún yìí làwọn èèyàn méjì mí-ìn tún gbọ̀nà ọ̀run lọ nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́.

Oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan ni Fidiwọ wa. Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, eeyan mẹrin lo ku ninu ijamba ọkọ nibẹ, awọn mejila fara pa. Ohun ti ọga FRSC Ogun, Ahmed Umar, ṣalaye ni pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan kọja iṣẹju mọkandinlogun ni ijamba to gbẹmi eeyan meji yii waye.

O ni jiipu Lexus ti nọmba ẹ jẹ AKD 405 AQ lo n sare buruku bọ, to lọọ kọ lu tirela to ni nọmba JJJ 532 XM latẹyin.

Bi dẹrẹba to wa jiipu ṣe da a bo tirela ni ijamba ṣẹlẹ, ti eeyan meji ku loju-ẹsẹ ninu awọn mẹrin to wa nibẹ. Kọmandanti Umar sọ pe ijamba to ṣee dena ẹ ni awakọ jiipu yii jẹ ko waye, to si ṣe bẹẹ pa eeyan meji danu.

Mọṣuari FOS to wa n’Ipara, ni wọn ko awọn to doloogbe naa lọ gẹgẹ bi Umar ṣe wi. O ba mọlẹbi awọn teeyan wọn ku kẹdun, o si ni ki wọn lọ sọfiisi FRSC Ogunmakin fun ẹkunrẹrẹ alaye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …