Home ÀKỌ̀TUN Ẹ jáwọ́ lórí ẹ̀kúnwó epo bẹntiroó tí ẹ̀ n gbèrò ẹ̀–Abdulsalami kìlọ̀ fúnjọba
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 22, 2022

Ẹ jáwọ́ lórí ẹ̀kúnwó epo bẹntiroó tí ẹ̀ n gbèrò ẹ̀–Abdulsalami kìlọ̀ fúnjọba

Ẹ jáwọ́ lórí ẹ̀kúnwó epo bẹntiroó tí ẹ̀ n gbèrò ẹ̀–Abdulsalami kìlọ̀ fúnjọba

Ọrẹ Òtítọ́jù

Olórí Orílẹ̀ yìí láyé ológun, Ajagun-fẹ̀yìntì Abdusalami Abubakar, ti kìlọ̀ fúnjọba pé kí wọ́n jáwọ́ nínú èròngbà láti fi kún owó táwọn èèyàn yóó máa ra jálá epo bẹntiroó, ó ní wàhálà àti ìnira gidi lọ̀rọ̀ náà máa mú wá fáwọn èèyàn, òṣì òhun ìṣẹ́ yóó sì túbọ̀ mu
ìlú dúndún.

Abdulsalami sọrọ yii niluu Abuja l’Ọjọbọ, ọsẹ yii, nigba to n sọrọ gẹgẹ bii olubanisọrọ pataki nibi apero kan tiweeroyin Daily Trust ṣeto rẹ.

Ọkunrin naa ni “lọwọlọwọ yii, nnkan bii miliọnu lọna ọgọrin awọn ọmọ orileede yii ni oṣi, iya ati iṣẹ n ba finra. Aito ounjẹ doju kọ orileede wa, ipenija arun Korona si tun da kun wahala ọhun.

Bijọba ba yọ afikun owo-ori epo bẹntiroolu kuro, ti nnkan naa si tun lewo si i, niṣe ni yoo sọ ọpọ ọmọ Naijiria sinu ebi, iṣẹ ati oṣi paraku, inira naa ko si ni i daa rara.

O rọ ijọba Buhari ki wọn ronu, ki wọn si wa awọn ọna mi-in ti wọn yoo fi pawo wọle labẹle, lai fi kun owo-epo.

Abdusalami tun ṣekilọ pe ọrọ eto idibo gbogbogboo to n bọ lọna lọdun 2023 yii gba ẹsọ pẹlẹ ati ọgbọn, nitori o le ṣakoba fun ajọṣe ati wiwa papọ orileede yii.

“Ẹ ṣakiyesi pe fun igba akọkọ, awọn gomina iha Guusu ati awọn gomina lati iha Ariwa orileede wa ti dojukọ ara wọn, kaluku lo n fẹ ki ipo aarẹ bọ sọdọ awọn ati agbegbe wọn.

“Idibo to n bọ yii gba pe ka simẹdọ gidi, ki ifẹ Naijiria si wa nipo akọkọ lọkan kaluku wa, ki orileede yii ma baa wo.

“Ẹ jẹ ka ranti pe yatọ sawọn ipenija ati idunkooko mọ ni to n koju Naijiria, ka wa lodidi ṣe koko, ba a si ṣe maa wa lodidi ṣe pataki.

Iṣọkan wa ati ba a ṣe pọ gbọdọ jẹ anfaani ati okun fun wa ni.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …