Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Guinea gbàjọba nílẹ̀ ọ̀hún
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 7, 2021

Àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Guinea gbàjọba nílẹ̀ ọ̀hún

Àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Guinea gbàjọba nílẹ̀ ọ̀hún.
Ọrẹ Òtítọ́jù

Ìdìtẹ̀gbàjọba ti wó ìjọba Ààrẹ Alpha Conde lulẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Guinea ni inú wọn kò dùn sí ìjọba Ààrẹ Conde lẹ́yìn tó wọlé fún ṣáà kẹta ní bíi ọdún kan dín díẹ̀ sẹ́yìn.
Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí Conde wọlé tán, ẹgbẹ́ alátakò náà kọjú ìjà sí iìjọba Conde.

Ile iṣẹ ologun gbe Conde, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin sí àhámọ́ lẹyin ti awọn eeyan gburo ibọn lẹgbẹ ile iṣẹ aarẹ ni Conakry.

Ọgagun GFS, Mahamady Doumbouya lo Kede lori ẹrọ amohunmaworan le awọn ologun ti gba ijọba.

Ọgagun Doumbouya ṣèlérí pé àwọn ologun yóò ṣètò lati gbe ijọba fún alágbádá.

O ni omi tuntun ti ri, ẹja tuntun Si ti wọọ lori ìṣèjọba orilẹ-ede Guinea bayii.

Ajọ AU, UN ati ECOWAS naa ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ologun ni Guinea.
Awọn yii fẹ ri pe awọn ologun gbe ijọba padà fún alágbádá ni kiakia.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …