Home ÀKỌ̀TUN Àwọn agbébọn jí Ẹmia gbé wọ’gbó lọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 6, 2021

Àwọn agbébọn jí Ẹmia gbé wọ’gbó lọ

Àwọn agbébọn jí Ẹmia gbé wọ’gbó lọ

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Èèmọ̀ lukutu pẹ́bẹ́, ìjì jà ó gbódó.
Láti alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta yìí làwọn jàǹdùkú agbébọn ti yí ibùsùn àti ìtẹ́ Dókítà Mahmud Ahmed Aliyu, Ẹ́míà ìlú Wawa Gbere, ní agbègbè Borgu, ní ìpínlẹ̀ Niger padà, dípò orí ìtẹ́, inú igbó lọba náà wà báyìí, àkàtà àwọn agbébọn tí wọ́n jí i gbé ló wà di bá a ṣe ń sọ yìí.

Ba a ṣe gbọ, niṣe lawọn agbebọn ti iye wọn pọ ya bo tinu tode aafin ọba ilẹ Hausa yii lalẹ ọjọ tiṣẹlẹ yii waye, niṣe ni ibẹrubojo da bo awọn eeyan nigba ti wọn n gburoo ibọn ni kọṣẹkọṣẹ, tawọn agbebọn naa si n wọnu gbogbo yara to wa laafin Ẹmia ọhun.

Wọn ni kabiyesi ọhun ti wa ninu iyẹwu pẹlu awọn iyawo ati ọmọ rẹ, taara tawọn agbebọn naa si wọ iyẹwu naa, niṣoju awọn mọlẹbi rẹ ọhun ni wọn fi gan ọba naa lapa mu,ti wọn si fidi ẹ jokoo tepọn sori ọkan lara awọn ọkada ti wọn gbe wa, o di inu igbo.

Wọn ni wọn o yinbọn pa ẹnikẹni, bẹẹ ni wọn o lu Aliyu tabi ṣe e leṣe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiọdun ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O sọ fun Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe loootọ niṣẹlẹ naa waye ati pe titi di ba a ṣe n sọ yii, awọn o ti i gbọ ipe latọdọ awọn agbebọn ti wọn sọ Ẹmia ilu dero inu igbo yii, bẹẹ lawọn o ti i mọ pato ibi ti wọn wa, ṣugbọn eto ti n lọ, iṣẹ iwadii naa ko si duro, lati doola ẹmi Ẹmia Wawa kuro lọwọ awọn afẹmiṣofo ajinigbe yii.

“Gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ yii la n gbe igbesẹ lati mu, ki wọn si jiya labẹ ofin, a si fẹẹ fọgbọn ṣe e ki wọn ma lọọ wu kabiyesi lewu,” gẹgẹ bi Abiọdun ṣe wi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …